Ambasedọ Yẹmi Farounbi gba àwọn olóyè ẹgbẹ oṣèré tiata ANTP lalejo - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 3 December 2023

Ambasedọ Yẹmi Farounbi gba àwọn olóyè ẹgbẹ oṣèré tiata ANTP lalejo

Lọsẹ to kọja ni Dokita Yẹmi Farounbi atawọn igbimọ to n sakoso ẹgbẹ oṣere tiata ANTP, gba awọn oloye ẹgbẹ naa tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan lalejo, nibi ti wọn ti ṣeleri lati ṣiṣẹ pọ pẹlu wọn.

Ipade ọhun to waye ni ọfiisi Ọjọgbọn Farounbi, niluu Ibadan, ni wọn tun ti gba awọn oloye naa nimọran lati ṣiṣẹ takuntakun lati le da ogo ẹgbẹ naa pada bọ sipo, ti wọn si n gbero lati ṣayẹyẹ nla  fun igbalejo awọn eeyan naa, eyi ti yoo waye ninu oṣu kin in ni ọdun 2024.

Ninu ọrọ Farounbi lọjọ naa lo ti sọ pe igba akọkọ ree toun yoo ri isakoso ẹgbẹ oṣere tiata ti wọn yoo ni aṣepọ pẹlu igbimọ to n sakoso wọn ati pe akọkọ ree ti inu oun yoo dun fawọn eto ti wọn ṣe pẹlu idaniloju pe awọn yoo fun wọn latilẹyin to ba yẹ.

 

Bẹẹ naa ni Alagba Oyewọle Olowomojuọrẹ, tọpọ mọ si Baba Gebu, naa gboriyin fun Dokita Rasak Ọyadiran, to jẹ aarẹ ẹgbẹ ọhun fawọn iṣẹ to ti ṣe. Lara awọn to wa nibẹ lọjọ naa ni Ọmọọba Adewale Adeoye Ẹlẹṣọ, aarẹ ẹgbẹ naa tẹlẹ, Ọgbẹni Rufai Abiọdun Oodua, Igbakeji aarẹ, Kọmureedi Ibrahim Mabolaje, akọwe ẹgbẹ, Arabinrin Adetẹju Agunlejika, Alukoro ẹgbẹ atawọn oloye mi-ii.

No comments:

Post a Comment

Pages