Ọpọ awọn agbẹ ni ẹgbẹ agbẹkọya ti sọ di oloorire-Aarẹ ẹgbẹ gbogbogboo - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 22 November 2023

Ọpọ awọn agbẹ ni ẹgbẹ agbẹkọya ti sọ di oloorire-Aarẹ ẹgbẹ gbogbogbooAarẹ ẹgbẹ gbogbogboo tawọn agbẹkọya,Oloye Kamọrudeen Okikiọla ti sọ ọ ṣọ di mi mọ pe ọpọ awọn agbẹ jakejado orileede yii ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ naa ni wọn ti di oloriire nipaṣẹ awọn anfaani ti wọn ti jẹ latigba ti wọn ti da a silẹ.

Aarẹ ọhun sọrọ yii nibi ipade oniroyin fun ti ayẹyẹ ọdun karundinlaadọrun ti wọn ti da iṣẹ ọgbin silẹ ati idagbasoke to ti de baa eyi ti yoo waye lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yiii iyẹn ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu yii, ni gbọngan BOS,LTV 8, Agidigbin, nipinlẹ Eko.

Gẹgẹ bo ṣe wi, o lawọn fẹẹ lo anfaani ayẹyẹ ọhun lati fi ṣafihan ibi ti igbalode ba iṣẹ ọgbin de, eyi to mu kawọn ọmọ ẹgbẹ naa pọ kaakiri.

Bẹẹ lo tun ṣalaye pe ki i ṣe ilẹ Yoruba nikan ni awọn agbẹkọya wa, o ni wọn ti tan kaakiri ilẹ Ibo ati ti Hausa nipasẹ eto ọgbin.

Oloye Okikiọla tun fikun ọrọ ẹ lati fi pe  awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ lati bawọn kopa nibi ayẹyẹ ti wọn fẹẹ ṣe ọhun. Lara awọn ti wọn n reti lọjọ naa lawọn Gomina lati ipinlẹ Eko, Ogun ati Ọyọ.

Bẹẹ lo ni Ọọni tilu Ile Ifẹ, Ọba Ogunwusi Ẹnitan yoo ṣaaju awọn ọba alaye yooku wa sibi ayẹyẹ ọhun.

Bakan ni Aarẹ ẹgbẹ yii tun lo akoko naa lati fi ẹmi imoore ẹ han sawon Gomina kan lori bi wọn ṣe fun wọn nilẹ lati maa fi ṣe ọgbin bẹẹ lo ni awọn kan ko fun wọn amọ wọn ro awọn agbẹ wọn lagbara lati fun wọn ni nnkan ti wọn yoo maa jẹ nipasẹ ọgbin.

Oloye Okikiọla tun sọ pe awọn yoo tun lo anfaani ayẹyẹ yii lati fi ṣeranti awọn akọni wọn fawọn ipa ti wọn ti ko latigba ti wọn ti da ẹgbẹ agbẹkọya naa silẹ.

Lara awọn to wa pẹlu aarẹ ẹgbẹ lọjọ naa Dokita Adegbenro Ogunlana,to jẹ akọwe Agbẹkọya lorileede yii,Oloye Ajibọla Salau,akapo ẹgbẹ wọn ati Oloye Ifalọla Onibode, toun jẹ Gomina wọn nipinlẹ Eko.

No comments:

Post a Comment

Pages