Ajọṣepọ to danmọran yoo tubọ wa laarin araalu ati aṣọbode nipinlẹ Ogun- Shuaib - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 22 November 2023

Ajọṣepọ to danmọran yoo tubọ wa laarin araalu ati aṣọbode nipinlẹ Ogun- Shuaib

Oga agba fajọ ẹṣọ aṣọbode nipinlẹ Ogun, Ahmadu Bello Shaibu, ti sọ pe aṣeyọri nla lawọn ṣe ninu owo to wọle ninu oṣu kẹwaa, ọdun yii bi wọn ba ni ki wọn fi wo ti ọdun to kọja, eyi to jẹ ida irinwo.

Nibi ipade oniroyin ti wọn se ni oluuleṣẹ wọn to wa ni Idi-Iroko, nipinlẹ Ogun,lọjọruu, Wẹsidee, onii, lo ti sọrọ ọhun.
O sọ pe gbogbo owo ti wọn pa wọle ninu oṣu to kọja naa jẹ N30,408,276.00, O sọ pe nnkan to jẹ ko ri bẹẹ ni ifarajin awọn oṣiṣẹ ati ajọṣepọ pẹlu awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ.

O salaye siwaju pe  gbogbo owo awọn ẹru ofin ti
 wọn gba lọwọ awọn fayawọ ninu oṣu naa jẹ
 N398,470,687.00.
Lara awọn ẹru fayawọ ti wọn ri gba gẹgẹ bi ọga agba ọhun ṣe sọ ni paali igbo, taya ati mọto Tokunbọ.Apo irẹsi to le ẹgbẹrun mẹrin atawọn nnkan mi-in.

Bakan naa ni Shuaib tun sọ pe lati le jẹ ki ajọsepọ to danmọran wa laarin ileeṣẹ naa ati araalu,awọn
ti bẹrẹ abẹwo kaakiri ọdọ awọn ọba alaye atawọn
ileeṣẹ nlanla.

Lara awọn ibi ti wọn ti de ti wọn ti gba wọn lalejo ni ọdọ Alake tilẹ Ẹgba, Ọba Adedọtun Arẹmu Gbadebọ,Ọlọta tiluu Ọta atawọn ọba alaye mi-in

O waa ṣeleri pe awọn yoo tubọ tẹsiwaju ninu ifarajin wọn lati ṣiṣẹ wọn gẹgẹ bi wọn ṣè yan an laayo.

   .              

                           .   

No comments:

Post a Comment

Pages