Won ti bere ayeye igbade Oba Macgregor, Olu Orile tiluu Ilawo - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 1 September 2023

Won ti bere ayeye igbade Oba Macgregor, Olu Orile tiluu IlawoGbogbo eto lo ti bere bayii fun ayeye igbade Oba Olusegun Macgregor,Olu Orile tiluu Ilawo, nijoba ibile Odeda, nipinle Ogun.

Gege bi Onarebu Ishaq Bada, to je alaga igbimo oye jije se wi nibi ipade oniroyin, o so pe ana Tosidee ni Oba naa kuro ni ipebi, nibi ti won ti sawon etutu kan fun un.

Leyin naa ni won tun sayeye ale adugbo, eyi ti won fi sami ayajo Ilawo.Bakan naa lo tun so pe aadorun ojo ni Oba naa lo ni ipebi, ko to jade sita.

Ni bayii, bi a se n ko iroyin yii lowo lawon elegbejegbe ti n loo ki Olu Orile Ilawo tuntun naa imurasile ayeye igbade ti yoo waye ni ola.

Leyin naa ni won yoo loo ki irun Jimo ni 
¹Ansarul-Deen Central Mosque, Orile-Ilawo.

Onarebu Bada tun fi kun oro e pe ojo naa tun ni "Oba MacGregor, yoo tun foye da awon eeyan jakanjakan lawujo lola.
 
Panbabari e no ayeye igbade ti yoo waye lojo Abameta, ojo keji, osu kesan-an, ni eyin gbongan asa ibile, Cultural Centre, Kuto

Lara awon ti won n reti lojo naa ni
Ooni tiluu Ife, Oba Enitan Ogunwusi, Alake tile Egba, Oba Adedotun Gbadebo; Osile ti Oke-Ona Egba, Oba Adedapo Tejuoso; Olowu tilu Owu, Oba Saka Matemilola atawon oba alaye yooku.

 
Nigba ti isin idupe yoo waye lojo Aiku, Sannde, ni soosi St. Peter African Church, Ilawo Abeokuta bere ni aago mewaa aaro.

Nigba to n soro akitiyan oba tuntun naa latigba to ti dori aleefa, Aare Babatunde,so pe oun gbosuba fun un lati ojo keeedogbon, osu Kerin tijoba ti gbe opa ase le e lowo fawọn ise takuntakun to ti see.


No comments:

Post a Comment

Pages