Abeokuta min titi lojo ti Rahman Ismail di Baaroyin ilu Sorobi - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday 5 September 2023

Abeokuta min titi lojo ti Rahman Ismail di Baaroyin ilu Sorobi
Titi di akoko yii lawon eeyan ilu Abeokuta nipinle Ogun, si n so nipa ayeye kan to waye lojo Sannde, Aiku, to koja yii bo se larinrin si, ti won mo pe okan lara Irawo oniroyin joye nla nigboro Egba.

Gbajumo akoroyin ilu mo on ka ni Rahman Niyi Ismail, ni Baale ilu Sorobi, Oloye Edward Dada Larunsi, fi joye Baaroyin ilu naa, eyi ti ayeye e waye no gbongan Executive, to wa ni Agbeloba, Quarry, niluu Abeokuta.

Ayeye ifinijoye ohun ni Baale naa fi sami ayeye odun kan to gori oye bee lo tun fi sojoobi ogota odun to dele aye.

Lojo ti Rahman joye Baaroyin naa, se lawon oba alaye kan wa nibe bee lawon Baale kaakiri wa lojo naa lati pon oga oniroyin to nileese iwe iroyin Akede News le.

Bakan naa lawon onitiata nii Baba Wande, Peter Fatomilola, Mama Awero, Alagba Omilani, Mama Ereko, Mama Efunsetan Aniwura, Iya Gbonkan atawon agba osere tiata mii in naa wa nibe lati pon on le.

Ko si le se ko maa ribe e nitori agba oje mi ninu ka a ko iroyin nipa amuludun, ooo awon osere yala onitiata ati olorin lo tipase e di eni taye mo.

Bakan naa ni Oloye tuntun nigboro naa, to tun nileese Journal Automobile Global Ventures tun gbekede lojo naa nitori bawon oniroyin se rogba yiika lojo naa.

Ninu oro Baale Sorobi lojo naa, Oloye Edward so pe ki i se pe oun kan fi Ismail joye Baaroyin, bi ko se pe oun topase e fawọn akitiyan e lawujo.

O ni aimoye idagbasoke ni Baaroyin ti mu ba ise iroyin ati pe ipa to ti ko se e fowo ro seyin. Bee lo tun sapejuwe e gege bi eni to loju aanu.

O wa gbadura fun un pe yoo ri emi  lo ati pe ola e yoo tubo maa tesiwaju.

Nigba toun naa soro lojo naa, Baaroyin dupe lowo Olorun fun bo se ka oun si, lati di eni to joye lojo naa 

Bee lomo bibi ilu Epe naa tun so pe Eko kan pataki toun ko ni pe ko ye ki eeyan maa se waduwadu, nibi ti ori yoo ba de laye yii dandan ni yoo de be.

Panbabari e ni ti Gbajumo olorin fuji nni, Sefiu Alao, to waa sere fun won lojo naa.

No comments:

Post a Comment

Pages