Shuaib di ọga agba asọbode tuntun nipinlẹ Ogun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 21 September 2023

Shuaib di ọga agba asọbode tuntun nipinlẹ Ogun


 



Ahmadu Bello Shuaib, ọga agba tuntun fun ileeṣẹ aṣọbode, ti wọn ṣẹṣẹ gbe wa si ipinlẹ Ogun, ti ṣeleri pe gbogbo ọna loun yoo gba lati ri i pe oun tẹle awọn aṣeyọri ti ẹni to kuro nibẹ bayii, Bamidele Makinde, ṣe lati le fi ṣe àtẹ̀gùn.

 

O sọrọ yii lakooko to n gba iṣẹ lọwọ ẹni to ti wa nibẹ, eyi to waye ni oluuleṣẹ ọfiisi wọn, to wa ni Idi-Iroko. O kọkọ dupẹ lọwọ ọga wọn patapata lorileede yii, Bashir Adewale Adeniyi, lori bo ṣe gbe oun wa si ipinlẹ naa pẹlu ileri pe oun yoo ṣiṣẹ to wa niwaju oun yii, gẹgẹ bo ṣe tọ ati bo ṣe yẹ.

 

Shuaib tun fikun ọrọ ẹ pe ẹni to ti ni oye nidii iṣẹ to wa niwaju yii loun oun yoo si ri i pe awọn yoo tubọ tẹsiwalu lati rii ipawo wọle ileeṣẹ naa tun gun rege. Bẹẹ lo tun gboriyin fun Makinde fawọn ipa ribiribi to ti ko lakooko to jẹ ọga agba, koun to gba akoso.

 

Ninu ọrọ Bamidele Makinde lakooko to n fiṣẹ le ọga agba tuntun lọwọ, o ki i ku oriire fun ipo to ṣẹṣẹ wa yii, o waa gbadura fun pe ki Ọlọrun ọba jẹ ko ṣe aṣeyọri nipinlẹ Ogun lakooko tiẹ. Bẹẹ lo rọ awọn oṣiṣẹ wọn lati tubọ fọwọsowọpọ pẹlu ọga wọn tuntun yii gẹgẹ bi wọn ṣe ṣe foun lakooko toun wa nibẹ.

 

Bakan naa lo fikun ọrọ ẹ pe gbogbo owo tawọn pa a wọle fun oṣu mẹtadinlogun toun fi wa nibẹ jẹ miliọnu igba o le mẹẹdọgbọn ati ẹgbẹrun mẹsan-an ati ẹẹgbẹrin naira ati aadọta naira.

N225,009,835.50.

 

O fikun ọrọ ẹ pe ninu miliọnu lọna Aadoje,ẹgbẹrun lọna ẹẹgbẹta le mejilelọgbọn ati kọbọ mejilelogun,naira. N136,532,168.22, tawọn pinnu  nileeṣẹ wọn.ṣugbọn awọn ri  miliọnu lọna ọgọfa naira o le meje ati ẹgbẹrun ọgọfa le meji N127,122,058.00. iyẹn ida mọkanlelaadọrun, ni eyi to ku oṣu mẹta ati bi ọjọ meloo kan ti wọn yoo fi pari ọdun.

 

Bẹẹ ni Makinde tun ṣatupalẹ awọn apo irẹsi bii  1,479,ọta ibọn 1,245,atawọn nnkan mi ti wọn gba lọwọ awọn fayawọ lakooko to wa nibẹ, o waa rọ ọga agba tuntun lati tẹsiwaju, lati ibi to ba iṣẹ de, ki wọn maa foju awọn fayawọ balẹ.

 

Abuja ni oluuleṣẹ wọn ni wọn gbe Makinde lọ nibi to tun ti lọọ jẹ ọga ni ẹka kan nibẹ,  to si ti bẹrẹ iṣẹ nibẹ bayii.

 


No comments:

Post a Comment

Pages