- BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 21 September 2023



Ambasedọ Olufẹmi Ajadi Oguntoyinbo, to jẹ ọkan lara oloye ẹgbẹ ninu ẹgbẹ oṣelu NNPP, to tun dije fun ipo gomina to waye nipinlẹ Ogun, ti sọ pe awada lasan loun ka idajọ to waye ti wọn fi yọ Abba Kabir Yusuf, gẹgẹ bi Gomina ipinlẹ Kano. O ni ẹfẹ nla loun ka a si.

 

Ninu atẹjade ti ọkunrin naa fi sita, to fọwọ si, lo ti sọ pe bigba ti wọn yi ẹjọ naa loun ri si niwaju igbimọ to da ẹjọ naa ati pe oun nigbagbọ pe ile ẹjọ kotẹmilọrun yoo yanju gbogbo ẹ.

 

Ọkunrin oloṣelu naa tun sọ pe ko sẹni to gbọ idajọ ọhun ti ko mọ pe wọn mọ ọn mọ yi pada ni ati pe ko awọn ko le gba iru ẹ, bigba ti wọn fẹẹ da wahala silẹ nipinlẹ Kano lawọn si ka a si.

 

Ajadi tun ṣalaye siwaju pe,’’ Awada ni emi ka idajọ ọhun si, Abba Yusuf, lawọn eeyan ipinlẹ Kano, finu fẹdọ wọn jade dibo fun-un. Awọn si ni wọn le gba a pada lọwọ ẹ, o da mi loju pe ti Oluwa ni yoo ṣẹ nigbẹyin’’

 

" Awọn onidajọ yẹn fagile ibo to waye nirọwọ rọsẹ, ti ko si wahala Kankan, ti wọn si dibo fun Abba Kabir Yusuf, gẹgẹ bi Gomina wọn tawọn adajọ waa fẹẹ gbe fun oludije APC, iyẹn Nasiru Gawuna.

 

"Awọn to n gbẹjọ naa ninu idajọ wọn ti ko lẹsẹ nilẹ yọ ibo165,663 kuro ninu eyi ti wọn di fun Gomina lati fi le ba ti ẹni ti wọn gbe ibo naa fun iyẹn oludije Gomina ẹgbẹ oṣelu APC. Pẹlu eleyii, o da mi loju pe idajọ ọhun lọwọ ojooro ninu’’

 

 

" Ẹgbẹ oṣelu wa, NNPP, ni ọmọ ile igbimọ aṣofin mẹrindinlọgbọn nile igbimọ aṣofin, nigba ti APC, ni mẹrinla. Ọjọ kan naa si ni wọn dibo mejeeji, o fẹẹ jẹ pe gbogbo ijọba ibilẹ la ti jawe olubori nipinlẹ naa, nibo waa ni awọn igbimọ to dajọ naa ti wa gbe aṣeyọri fun APC’’

 

 

Oguntoyinbo waa rọ gbogbo awọn eeyan ipinlẹ Kano atọmọ orileede yii lati ṣe suuru, ki wọn ma ṣe nnkan to lodi si ofun, nitori ile ẹjọ kotẹmilọrun lo maa yanju gbogbo ẹ. Bẹẹ lo tun rọ Gomina Abba Yusuf, lati ma ṣe boju wo ẹyin, ko tẹ siwaju ninu iṣẹ rere to n ṣe nipinlẹ Kano, nitori gbogbo awọn ọmọ ipinlẹ naa lo wa lẹyin ẹ.

 

 

Bẹẹ lo tun sọ pe, ‘’ Ẹ jẹ ki n sọ kinni kan fun yin, idajọ yii ko tu irun kankan lara ẹgbẹ oṣelu NNPP, nitori gbogbo eeyan lo mọ pe ẹgbẹ wa lo n ṣaaju nipinlẹ naa, nitori idi eyii, igba perete ni idajọ naa’’

 

O waa gboriyin fun Sẹnetọ Rabiu Musa Kwakwaso lori awọn igbesẹ rẹ, to si fi n dari ẹgbẹ naa.

 

 

 


No comments:

Post a Comment

Pages