Nitori Muri Thunder ni mo ṣe fa sẹyin lọdọ Saidi Oṣupa, amọ gbogbo ẹ ti yanju bayii- Tọpẹ Nautical - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 16 September 2023

Nitori Muri Thunder ni mo ṣe fa sẹyin lọdọ Saidi Oṣupa, amọ gbogbo ẹ ti yanju bayii- Tọpẹ NauticalOhun to n lọ nigboro nigba kan ni pe aarin gbajumọ olorin fuji nni Alaaji Tọpẹ Nautical, tọpọ mọ si ọmọ Iya Aye, ati ọga e, Saidi Oṣupa ko danmọran, ṣugbọn laipẹ yii lo pada lọọ ki ọga ẹ, ti wọn si yanju aawọ to wa laarin wọn.

Ṣugbọn laipẹ yii ni ọkunrin naa gba ẹgbẹ awọn oniroyin Yoruba lalejo nibi to ti sọ nipa iriri ẹ nidii iṣẹ to yan laayo ati nnkan to da wahala silẹ laarin oun ati ọga ẹ, awọn ibi ti fuji ti gbe de atawọn to pinnu fun ọjọ iwaju.

Ọrọ to ba wa sọ ree;

 

Ta ni Tọpẹ Nautical?

 

Orukọ temi ni Alaaji Tọpẹ Nautical ọmọ Iya Aye, ṣẹ ẹ mọ pe bi iya eeyan ba ku, iya naa ni yoo ku, ẹ ma jẹ ki n fa a gun ju bẹẹyẹn lọ. Iya o si mọ, gbogbo awọn iya to ku, iya mi.

 

Laipẹ ni a ri yin nile Alaaji Saheed Osupa, ki lo fa igbesẹ yii?

 

 

 

Bẹẹ ni mo lọ sile ọdun ni. Ṣe ẹ mọ pe ọga mi ni, lati ọjọ to ti pẹ, bẹẹ naa ni ọga mi naa ni Wasiu Alabi Pasuma.

 

Nnkan to ṣẹlẹ ni pe ṣe ẹ ri nigba min-in bi eeyan ṣe maa n ro bo ṣe fẹ ree,  ti Ọlọrun yoo  jẹ ko ri bakan, nidii iṣẹ fuji yii, awa ti n reti awọn igbesẹ kan, igbesẹ ti Alaaji Saidi Oṣupa n gbe lẹnu ọjọ mẹta yii n wu emi funra mi lori, o si du mọ mi pupọ.

 

O lọ si ọdọ Pasuma, o lọọ ki wọn fun ti mama wọn to ku, o wu mi lori gan-an ni, ni  mo fi sọ pe ọga yii. ọga daadaa to n fẹ ki alaafia joba lagboole fuji ni. Awọn nnkan wọnyii ti irẹpọ ba ti waye laarin awọn ọga wa,  awokọṣe wọn ni awa ta a n bọ lẹyin wọn yoo maa wo ta o fi maa ṣiṣẹ, nitori awọn to n bọ lẹyin ti wa naa. Ni kikun, iyẹn ni ko ni jẹ ki iṣẹ fuji parẹ.

 

 

 

Awa la ti n gbẹnu le aadọta ọdun bayii, awọn Paso naa ni wọn wa lọjọ ori ti wọn wa. Awọn wo ni a wa fẹẹ fi fuji yii silẹ fun. Nigba to ba jẹ pe gbogbo igba ija, awọn igbesẹ ti Alaaji Saidi gbe yii wu mi lori gan-an ni. Ohun lo fa sababi  ti emi naa fi lọ ba wọn ti mo fi lọọ bẹ wọn.

 

 

 

Ṣe igbesẹ ti Oṣupa gbe lati lọọ ba Pasuma, lo ta yin nidii lati lọọ ba a nile?.

 

 

 

Latilẹ ọga mi ni Saidi Osupa, itan wa ko ṣee fi pamọ, ti gbogbo awọn aye mọ. Ati pe awọn ara kan ti mi o fẹẹ ma tun sọ mọ ni. Ṣugbọn,  bi eeyan ba bi ọmọ mẹta, to ba tiẹ fẹran ọkan ju, o yẹ ko  fi ọgbọn ṣe e ni, ko ni i gbe e soju, to ba gbe e soju, yoo kan dabii ẹni pe awọn yookuko ja mọ nnkan kan ni.

 

 

 

Bi emi ṣe wa yii, onikaluku lo mọ ibi to ti n bọ,  ọmọ Mushin ni mi, ibẹ ni wọn bi mi si, ti mo si dagba si, mi o ni lati sọ pe mo fẹẹ lọ si Ajegunlẹ lati mọ nnkan ti wọn ṣe nibẹ,Emi ati Saidi Oṣupa ti mọ ra tipẹ.

 

 

 

 Nigba ta a wa lọdọ wọn, mo ba  Sardon 2, nibẹ ni. Iyẹn Kamọru, ṣugbọn  wọn mu Muri Thunder waa ba nibẹ ni. Gẹgẹ bi awọn agba ṣe maa n sọ, ohun to ba wu ọba lo le fawọn ẹru ẹ ṣe, Ọlọrun ma ṣe wa ni ẹru.

 

 

 

Bi emi ṣe maa n ronu gẹgẹ bi ọmọ igboro, mo kan ro pe nigba yẹn ni pe ki n sunmọ ẹyin, ko si ori wa nibẹ mọ niyẹn.

 

 

 

Bi awọn wo?

 

Ohun to ṣẹlẹ ni pe mo ti sọ fun Alaaji Oṣupa ọjọ ti mo lọ sibẹ, mi o fẹ tun maa pada sẹyin, nitori bi agboole fuji ṣe n lọ, mi o fẹẹ sọ nnkankan to le da wahala silẹ. Emi o ki i ṣe alabosi, ko si ẹni ti mi ko le sọrọ loju ẹ.

 

Ohun to si sẹlẹ ko ṣe fi i pamọ, nigba ti awa mẹta wa lọdọ Oṣupa nigba naa, gbogbo wa la fẹ ni ẹbi, ta a si fẹẹ jẹ eeyan nidii iṣẹ fuji. Nigba taa si ri i pe ẹnikan ti wọn fẹran ni wọn da yọ sọtọ, gbogbo ẹtọ ati ipolowo to yẹ ki a ma jẹ ni Oṣupa ṣe fun Muri.

 

Ohun si lawọn eeyan n ri, ko si ọmọ Oṣupa ti ko mọ orin kọ.Eyi ti ọga wa fi han awọn eeyan, oun ni wọn n ri, ti wọn jẹ bii ṣawama.iyẹn dun mi, to si mu mi fa sẹyin,ti mo si tẹsiwaju.

 

 

 

O ti ṣẹlẹ tipẹ o, o ti n lọ bi ọdun mẹwaa ti emi ti kuro ni  mo sọ .igba to ṣẹlẹ gbogbo wa ko ti i ṣe ju rẹkọọdu meji si mẹta lọ

 

 

 

Gbogbo igba taa wa ti wọn ko ti i ya iṣẹ fun wa, olorin ni wa, ṣugbọn ẹyin ọga wa ni a wa.

 

 

 

Alaaji, Mushin ni ẹ wa, ti ẹ ti n kọrin, torukọ yin ti yọ, ki lo de ti ẹ ko fi jokoo sọdọ Pasuma, to jẹ pe ọdọ Saidi ni ẹ lọ?

 

 

 

Ṣe ẹ ri emi, ṣọọṣi ni mo ti bẹrẹ iṣẹ orin temi,ni Mushin nigba naa, ibi tawa olorin ti maa n kọrin pọ, o si maa fẹẹ jọ ara wọn, emi si maa n fẹ ki nnkan ko yatọ. gbogbo igba ti mo n sọ yii ti mo dọmọ onifuji, lẹyin ti mama mi ku ni mi di ọmọọta, gbogbo igba ti wọn wa laye, ile ni mo wa o.

 

 

 

Emi maa n lọ si Ajegunlẹ, nitori mo maa n kaakiri ọmọ igboro ni mi,  mo maa n lọ sibi ti Oṣupa ti maa n kọrin, mo ri i pe mo sunmọ wọn lẹyin ti wọn ṣe orin kan ti wọn gbe wọn wa si Mushin.

 

 

 

Fun ara mi ni mo lọ sọdọ ẹ, ti mo lọ fi ara mi han, oun kọ lo fun ni Oṣupa keji o,nitori nnkan tawọn eeyan fi mọ mi nigba naa ni. o si gba bẹẹ. Igba to ya, ṣe ẹ mọ pe eeyan maa n gbọn si i nidii iṣẹ yii, emi naa ri awọn to fẹẹ ran mi lọwọ ṣe rẹkọọdu.

 

 

 

 ni mo waa ro pe ko yẹ ki n maa ṣe Oṣupa keji, nitori ko si nnkan ti mo le maa fọwọ bo, orukọ ti mo maa jẹ bayii ni Tọpẹ Nautical, ki n ma fi nnkankan mi-in  si i. Mo ṣe rẹkọọdu kan nigba naa,  Confirmation ni mo pe e , awọn eeyan si gba a.

 

 

 

Ni gbogbo igba naa o loju nnkan teeyan gboya fun lati sọ tabi ṣe, nigba ti mo fẹẹ ṣe rẹkọọdu yẹn. Awọn eeyan lo gbe e kalẹ, o si n lọ. Nnkan to ko jẹ ki n duro ni Mushin ni mo n sọ fun yin yii o.

 

 

 

Ki n too kuro ni Muṣhin Pasuma jẹ ẹni to dara si mi, emi nikan kọ, atawọn onifuji yooku ni. Ti a maa n ri ile ẹ wọ daadaa, to ba ti wọ ibẹ bayii, waa rẹrin-in jade ni. Bi emi tiẹ ṣe wa yii, mo n ṣe ipata gan- an ni, aimọye ẹjọ ni Pasuma ti ba mi yanju ni teṣan.

 

Ko too di pe  Pasuma kuro ni Mushin, to n gbe ni Isọlọ, awa ṣe ipata gan-an ni, ọjọ kan ni Pasuma pe mi pe ṣe orin ni fẹẹ maa kọ ni tabi ija ni mo fẹẹ maa ja.Ẹgbọn gidi lo jẹ si mi, ko too di pe mo tun lọọ wo nnkan ti wọn n ṣe ni Ajegunlẹ.

 

Nnkan ti mo kọ lara Oṣupa ṣi wa lara mi, nnkan ti mo kọ lara Pasuma naa si wa lọwọ mi. Nitori fuji ta an ṣe yii naa, eeyan gbọdọ kọgbọn kaakiri ni,wọn fun mi ni nnkan ti mo fẹ, emi ri nnkan ti mo fẹẹ lọdọ wọn, wọn kọ mi bi eeyan ṣe n ṣe orin, wọn fun wa ni igboya lati le gbe orin kalẹ.  Bawọn purodusa ba fẹẹ fun ẹ niṣẹ, bi wọn ba ri bi iwọ gan-an ṣe n kọrin, wọn a kọkọ sun mọ ẹyin.wọn a jẹ ko danmọran, mo ri nnkan ti mo n fẹ lọdọ Oṣupa. Nnkan kan to mu mi sun mọ ẹyin naa ni mo ti sọ saaju.Pasuma tẹ n pariwo, to ba debi bayii, yoo di ẹgbẹ gbogbo wa ni, iwọ to ba ri, lo ri.

 

 Bawo waa ni ẹyin ati Muri Thunder?

Awọn eeyan kan  maa n sọ isọkusọ ni, ẹ o le beere lọwọ ẹ, ko ni oun ati Tọpẹ ja laelae,a nija , igba ti mo sọ pe mo sun sẹyin lọdọ Oṣupa, ko pẹ ti mo kuro nibẹ ni  mo gbọ pe Muri n bu Saidi Oṣupa, ara mi o gba a, mo bẹrẹ si ni i da a lohun,igba ti mo ṣe diẹ, ni mo ba pinnu lati kuro nibẹ, ti mo kọju mọ iṣẹ mi.

 

 Bawo lo ṣe ri lara yin pe ẹ ri eeyan bi Wasiu Ayinde, nibi apejẹ lọjọ ti Tinubu gbajọba?

 

Ṣe ẹ ri awọn nnkan ta n reti pọ, diẹdiẹ naa ni.Lakooko yii, Aarẹ wa Tinubu ololufẹ fuji ni wọn, lati aye Sikiru Ayinde Barrister,ki Ọlọrun fọrunkẹ wọn, nisinyii, Mayegun lo wa nibẹ,ki Ọlọrun jẹ ka ri wọn pẹ.

Mo ri pe bi wọn ṣe wa nibẹ, ọlọpọlọ pipe ni Wasiu Ayinde, mo nigbagbọ pe wọn yoo ti maa gbe igbesẹ kan pe eeyan ti wa lo nibẹ, oun ni apẹẹrẹ eyi ti ẹ sọ lẹẹkan,ṣe ẹ mọ pe onifuji kankan ko ṣe iru nnkan bẹẹ. A tun fẹ nnkan to le ṣe wa ni anfaani.

 

Nibo lọpọn orin sun Tọpẹ Nautical de?

 

Ẹ jẹ ka ma dupẹ, mo ti lọ South Africa, Ghana, Dubai,awọn kan wa ti mo fẹẹ sọ nibi, to maa ṣẹlẹ lọdun yii, nitori nnkan ta a ba bo, lo ma n niyi.Asiko ta a wa yii, mo n lọ so Egypit, Kenya, , ilẹ Africa ni, mi o ti lọ si London ri,  mi o ti lọ si Amẹrika

 

 Nigba ti wahala bẹ silẹ laarin Arabanbi ati Olufimọ. N jẹ o fẹẹ fa yin laṣọ ya?.

 

 Haa!, O lagbara gan –an ni, nitori mi o fẹẹ da si i, mi o ṣe mejeeji, nitori mi o fẹ ni wahala pẹlu ẹnikẹni, o fẹẹ dabi ẹni pe Tọpẹ Nautical, ko mọ orin kọ mọ nigba naa. Nigba ti Pasuma da ọga nla silẹ, emi ni onifuji akọkọ to kọkọ fọwọ si i,  mo ni o se sọ, idi ni pe nnkan to ṣelẹ  laduugbo mi, tikẹẹti ọmọ Muṣhin, ni mo fi wọle, kin ni yẹn ti di igun nigba naa, to ba ṣe Ọganla, wọn ko ni i mọ pe o mọ orin  ikọ, to ba si se Ọga nla bakan naa ni, ọtẹ naa ni gbogbo ẹ.


Description: https://lh3.googleusercontent.com/a/ACg8ocILVYeh6eUmnxwOC11qJZ-WMUfJlowr7dVNHS5FNG8G=s40-p-mo

No comments:

Post a Comment

Pages