Dokita Babatunde Adeyẹmọ, gbajumọ ninu awọn to n ta ilẹ, to ṣee gbọkanle,laini idunkoko kankan, to nileeṣẹ Pelican Valley Nigeria Limited, Ọmọwe Babatunde Adeyẹmọ, ti rọ gbogbo awọn to wa ni Oke-okun lati fọkan wọn fun idokoowo lori ohun to jẹ mọ ilẹ ati dukia lakooko yii, nitori pe igba yii lo dara ju laini ifoya kankan.
O sọ pe asiko ti owo pasiparọ dọla ti gbẹnu soke lairotẹlẹ yii gan-an ni yoo jẹ akfaani fawọn to n gbe oke- okun lawọn ilu bii Canada, Ireland, USA, United Kingdom ati bẹẹ bẹẹ lọ le pinlẹ dokoowo lori dukia.
O ṣalaye siwaju pe ko yẹ kawọn to wa ni oke-okun maa jẹ ajẹbanu lakooko yii, wọn gbọdọ ronu awọn nnkan ti wọn le maa fawọn owo ti wọn ba ni lọhun de awọn nnkan gidi mọlẹ lorileede yii, nitori owe awọn agba kan to sọ pe ile ni abọ isinmi oko.
Bẹẹ ni Ọmọwe Adeyẹmọ tun fikun ọrọ ẹ pe aye wa fawọn eeyan ọhun lati wa jẹ ninu anfaani ti ileeṣẹ Pelican Valley Nigeria Limited gbe kalẹ fun awọn ọmọ Naijiria, ti wọn ti fi orileede yii silẹ tipẹ, ki wọ le rawọn nnkan ba a ti wọn ba pada dele.
Adeyẹmọ, ẹni to tun jẹ Ambasadọ fawọn ọdọ ilẹ adulawo, iyẹn ECOWAS Youth Ambassador ati Ambasadọ lori igbogunti iwa ajẹbanu, ‘’Anti-Corruption Ambassador’’ ṣalaye siwaju pe lara ojuṣe wọn ni lati ṣafihan awọn anfaani ti wọn ni nilẹ fawọn onibaara.
Iroyin fi to wa leti pe, gbogbo eto lo ti to fun oludasilẹ ileeṣẹ Pelican Valley Nigeria Limited, lati kopa nibi ipade kan ti yoo waye niluu London, lọjọ keji, oṣu kejila, ọdun 2023, ti wọn pe ni ‘London AVI Networking Event 2023’, nibi ti wọn yoo ti maa sọrọ nipa dukia, ati bi wọn ṣe n ṣabojuto dukia lorileede Naijiria.
A gbọ pe ileeṣẹ kan ti wọn pe ni Avenue Impact Training & Consulting Limited, eyi to n ran awọn eeyan lọwọ nipa iṣẹ ti wọn le ṣe lo ṣagbekale eto ọhun, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
Bẹẹ la tun gbọ pe ipinnu Ọmọwe Adeyẹmọ ni lati jẹ ki ileeṣẹ Pelican Valley Nigeria Limited, mu anfaani nla ba ipinlẹ Ogun, nibi ti miliọnu kan Euro nipasẹ didokoowo lori dukia.
No comments:
Post a Comment