Iya n jẹ araalu awọn oloṣelu ti ba nnkan jẹ jinna, atunṣe nikan lo ku- Ambasedọ Olufẹmi Ajadi Oguntoyinbo - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 15 June 2023

Iya n jẹ araalu awọn oloṣelu ti ba nnkan jẹ jinna, atunṣe nikan lo ku- Ambasedọ Olufẹmi Ajadi OguntoyinboAmbasedọ Olufẹmi Ajadi Oguntoyinbo, oludije gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu NNPP, nipinlẹ Ogun, gba BOṢERI lalejo,o sọrọ ilẹ kun lori awọn iriri ẹ lakooko ipologo ibo to waye, ipo ti ẹgbẹ naa wa bayii ati ipinnu ẹ nipa oṣelu lọjọ iwaju. Bakan naa lo tun mẹnuba isakoso ijọba to n lọ lọwọ lorileede yii labẹ akoso Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu. Awọn nnkan to ba wa sọ niyii

Njẹ ẹ le sọ fun wa awọn iriri yin lakooko ti ẹ jade dupo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu NNPP nipinlẹ Ogun?

Adupẹ lọwọ Ọlọrun ọba pe o mu wa lọ, ninu irinajo ibo to kọja, o si mu wa pada bọ, O jẹ kayeefi fun mi pe ai bawọn si nibẹ ni ai bawọn da si, gẹgẹ bi owe, boya ki n sọ pe Ọlọrun ko tii ran awọn alaanu aṣaaju  sawọn ọmọ Naijiria ni.

Tabi ki n sọ pe akoko ko tii to lati ni awọn olori to ṣe fi yangan lawujọ, nitori ti a ko ba gbe igbesẹ lati dije ni, a le ma mọ iya ti awọn ọmọ ipinlẹ Ogun farada,lati ọdun pipẹ sẹyin,amọ apoti ti mo gbe yii jẹ ki a ri gbogbo kọrọ, to wa ninu iṣẹ oṣelu.

Awọn kan maa n sọ pe oṣelu idije iwọsi ni, amọ emi o ri bẹẹ rara, awọn to fẹẹ ṣe oṣelu gan-an ni oniwọsi. Nitori iwọ too ba ni inu daradara, to ni inu ire, to ba wa sinu oṣelu tabi to fẹẹ darapọ mọ awọn ti ko ni ọpọlọ lati le dari orileede, ni iwọ naa ti darapọ mọ awọn oloṣelu oniwọsi.

Ṣugbọn to ba jẹ pe iha to kọ pe oṣelu n bọ to fẹẹ ki orileede Naijiria dọtun, to si fẹ kawọn ọmọ abẹ ẹ gbadun ohun ọtun, ẹ o rii pe a o ka oṣelu si ohun iwọsi. O jẹ kayeefi pe gbogbo awọn oloṣelu ta a ni lorileede yii ko ṣetan lati tun ilu ṣe, to si jẹ pe wọn n lọ kaakiri orileede agbaye.Emi o roo pe ohun ti wọn lọ ṣe ni lati mọ bawọn yẹn ṣe n ṣe, nitori to ba jẹ bẹẹ ni o yẹ ki a ri apẹẹrẹ ẹ lati ara wọn

Eyi jẹ ko ye wa pe awọn olori wọnyii to yẹ ki wọn lọ sibẹ boya wọn lọọ kowo wa pamọ ni o, ki lo tiẹ fẹẹ maa mu yin sa kaakiri, bi ẹ ba ni oriṣiriṣi igbafẹ ni Naijiria, ti ẹ si lowo,  eyi jẹ ko ye wa pe awọn olori taa ni lo ku diẹ kaato si lọwọ, ki i ṣe ọrọ aje ilu yii.

Eyi lo jẹ ki n le ranti awọn idojukọ mi lakooko naa gẹgẹ bi iriri mi,nitori pe Oluwa ran mi wa lati wa gba ọmọ Naijiria silẹ,mo maa sọ fun gbogbo ọmọ araye atọmọ Naijiria pe emi ti wọn n wo yii, mo wa lati ni orukọ ju Awolọwọ lọ ni, mi o wa lati lorukọ bi Awolọwọ.

Mi o wa mọ iye ọjọ ti mo da lo jẹ ki n maa ṣotiitọ ti Ọlọrun ran mi,awọn to n ṣoju orileede yii lọwọ, a n gbadura fun aarẹ tuntun to debẹ ki Ọlọrun lo,o to bi si ti loo o di dandan ki iyatọ deba orileede yii.Gbogbo ipolongo mi, mo rii pe awọn eeyan jiya pupọ, wọn ko si nigbagbọ ninu awọn oloṣelu, wọn jẹ ko ye wa pe bi ẹ ba ti debẹ, ẹ ko ni nnkan ti ẹ fẹẹ ṣe fun wa mọ, wọn a ni ka fawọn ni tawọn bayii.

Mo ranti awọn ọdọ bi igba ti wọn ko ibọn pade mi ni Ọja-Ọdan ni Yewa North, ti wọn jẹ ko ye mi pe ta lo jẹ ki n wa sibẹ, ki lo de ti mo fi wa, ati pe kin ni mo waa ṣe, nigba ti wọn ri bi mọto to tẹle ara wọn, ti wọn rii pe ipolongo ni a wa ṣe.

Wọn dena de wa, mo waa roo pe akoko naa ki i ṣe ka yinbọn lu ara wa,nipa aṣaaju rere ni,wọn da mi duro ninu mọto, wọn ni ki nduro, ti mo ba ni ki n gbe ẹsẹ, wahala yoo bẹ, ọrọ yii ni mo gbọ ti mo fi sọ pe ki dẹrẹba mi duro, nitori mi o lọọ lati ta ẹjẹ silẹ, bi ko ṣe pe a lọ sibẹ lati jẹ ki wọn mọ ootọ to yẹ ki wọn mọ. Fun wakati meji ni mo fi duro, ti wọn sọ pe miliọnu lọna ẹẹdẹgbẹta lowo awọn.

Owo kin ni? Wọn ba ni, ṣe wọn ko sọ fun yin ki ẹ to wa tabi ẹ ro pe ẹ ko ni kọkọ wa ba awa nibi.Wọn ni ki gbogbo awọn alaabo to tẹle mi lẹyin, ki wọn yinbọn wọn lẹyin ọgbọn iṣẹju tan, wọn ni ti wọn ko ba fẹẹ yin, ki wọn ko gbogbo ibọn naa silẹ.

Kayeefi lo jẹ fun mi ki ọmọ Naijiria maa sọ fun alaabo ilu ẹ pe ko ko ibọn ọwọ ẹ silẹ. Itumọ ni pe awọn olori sẹyin nipinlẹ Ogun, ati lorileede yii lapapọ, wọn ko nawọ idagbasoke sawọn agbegbe kan, eyi lo jẹ ki wọn ni ọmọọta to pọ.

Bẹẹ lawọn kan wa ti ọna wọn ko ṣe e rin, bawo la ṣe bawọn yẹn sọrọ, ti wọn roo pe awa taa tun ṣẹṣẹ n bọ yii bakan naa lo ma jẹ.

Lẹyin ti ibo ti waye sẹyin, kin ni nnkan ti ẹ n ṣe lakooko yii?

Nitori nnkan ti ko ye awọn oloṣelu Naijiria, o ye awa ta a n bọ lọna, nitori pe wọn ko mọ nipa oṣelu, oun lo  fẹ ki n dọgbọn kọrin ti Saidi Oṣupa kọ fun wọn. Pe awọn ti wọn mọ nnkan ti wọn n sọ , wọn ko sọrọ,awọn ti wọn ko mọ nnkan ti wọn n sọ ni wọn wijọ o.Awọn ti wọn mọnnkan ti wọn n ṣe, wọn ko ṣe oṣelu,  awọn ti wọn ko mọ nnkan ti wọn n ṣe, ni wọn n wa kaakiri.

Awọn ti wọn mọ ti wọn n ṣe won ko ṣe oṣelu, amọ awọn ti wọn mọ nnkan ti wọn n ṣe ti waa da si bayii. Mo fẹẹ wa lara awọn to n wo awujọ, ti yoo si maa sọ bi wọn ṣe n tukọ ẹ lọwọlọwọ. Nitori  ko yẹ ki a maa sa kaakiri ẹgbẹ oṣelu, to ba jẹ pe a mọ nnkan taa n ṣe.

A kan ni lati maa jiroro bi ipilẹ ẹgbẹ ṣe yẹ ko maa lọ. Ki i ṣe ka maa sa kaakiri, awọn to n sa kiri yẹn ọjẹlu ni wọn, wọn ko mọ oṣelu, nitori to ba mọ oṣelu daadaa fọmọ araye, ko to debẹ awọn kan yoo nifẹẹ ẹ, ti wọn yoo maa tẹle ẹ lẹyin, amọ to jẹ pe o ṣe nnkankan o fẹẹ jẹ iṣẹ,too ṣe silẹ, oun lo jẹ p koda bi ẹni pe awọn kan maa n sọ pe ọga mi ti n lọ ẹgbẹ oṣelu kan, emi naa maa lọ, ko dara bẹẹ., ṣugbọn to ba jẹ pe ọga niwọ naa, to le duro ti wọn lọrun, atunto la fẹẹ to, a si bẹrẹ lati ori ẹyin, ti ẹ n ṣe alaga ni, abi ẹyin ọmọ ẹgbẹ, nitori a ko ko ara wa nijanu lo jẹ ki onikaluku wa maa ṣe yannayanna, ti mo ba fẹẹ ṣe apẹẹrẹ, ẹ wo iru Ganduje, to n sọrọ si ọga ẹ, ti ko too wo loju, Kwakwanso.

Idi ti mo fi sọ pe tọọgi lo wa ni ọfiisi gomina tẹlẹ, to sọ pe oun fẹẹ gba gomina tẹlẹ bi tiẹ leti,ki lo fẹẹ gba leti fun, kin ni ẹ ẹ ba maa fa, ṣe o pa ọmọ ẹ ni, abi o ba iyawo ẹ sun.koyẹ ko ri bẹẹ.

Nibo ni ẹ ba ẹgbẹ NNPP de bayii nipinlẹ Ogun?

Ẹ ṣe pupọ, bi  ẹ ba ri gbogbo atẹjade ta a ti tẹ sẹyin, a ti jẹ ko ye gbogbo ọmọ ipinlẹ Ogun pe alaga tẹlẹ, Sunday Ọginni, wọn ti yọ ọwọ ẹ kuro laṣọ, a si ti yan fidihẹ, orukọ ẹ ni Ọmọọba Ibarahim Adekunle, a ko tii ṣe ipade gbogbogboo, ta a ba ṣe ni a o yan alaga, amọ ni bayii, baba yẹn ni wọn sọ pe ko maa tukọ ẹgbẹ lọwọ.

Eyi to wa nibẹ tẹlẹ nitori gbogbo awọn iwakiwa to hu, to n gba lọwọ awọn ẹgbẹ oṣelu mii-in, to fi  oṣelu ṣe katakara ni a ṣe yọ ọ danu.Ṣugbọn ọmọ ologo ti wọn n sọ lọwọlọwọ ni Adekunle.

Bawo waa ni ọjọ iwaju ẹgbẹ oṣelu naa nipinlẹ Ogun?

Ṣe ẹ rawọn to wa nibẹ tẹlẹ, ara awọn aṣiṣe ti wọn ti ṣe sẹyin,wọn ni awọn nnkan taa n pe ni Structure, ọmọ ẹgbẹ kaakiri, onijibiti si ni wọn. Ọmọ ẹgbẹ  ti wọn maa n sọ pe ọga ẹ ta a ni ko fun wa lowo, ti ko ba fun wa, a maa duro tii lọrun. A ma ba a fa a , a maa ko gbogbo ọmọ ẹgbẹ lọ fi gbowo, wọn fi n ṣowo katakara. Ṣugbọn ni bayii, a ti n ṣe atunto ọmọ ẹgbẹ lati wọọdu de ijọba ibilẹ.

Pẹlu bi ẹ ṣe jawe olubori ibo to kọja, ṣe ki i ṣe pe opin ti de ba awọn iranwọ yin fawọn eeyan?

Ṣe ẹ mọ pe ẹni ti Ọlọrun ba ti ṣoore fun ko si ẹda eeyan to le bii lulẹ, Oluwa ran wa saye lati waa gba awọn ọmọ orileede yii silẹ, to ba jẹ pe China lo da mi si tabi fẹẹ ki n wa, ohun to gbe le mi lọwọ, mo gbọdọ ṣe e. Nitori idi eyi iṣẹ ti Oluwa ran mi, a fi dandan ki n jẹ.

Ohun to ran mi ni lati lọọ maa wa alaafia ati idagbasoke orileede Naijiria, nnkan ti mo gbe da ni yii ko si si nnkan to le fa mi lọwọ sẹyin, lati maa tu ọmọ orileede Naijiria kuro ninu ide, fun idi eyi, ko si nnkan to ni ki n ma ṣe daradara fun wọn.

Ijọba ta a ṣẹṣẹ bẹrẹ yii, bawo ni ẹ ṣe ri si?

Igbesẹ ti Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu ti gbe sẹyin, awa ṣẹṣẹ gbọ pe Buhari ti fọwọ si yiyọ sọbsidi owo epo kuro nibẹ, ki lo de to fi jẹ pe nigba ti wọn debẹ ni wọn ṣẹṣẹ kede, ti Buhari ko sọ sita. To ba waa ribẹ, n jẹ ki lo de tawọn ko ni suuru, ki wọn to polongo, nitori wọn ṣẹṣẹ wọ ijọba ni.

Ṣe ijọba ti wọn waa ṣe ọdaju ni tabi to n fẹẹ tọju ọmọ Naijiria, to ba jẹ eyi to maa tọju wọn ni, o maa dun, o maa ni oyin, amọ ti ko ba ri bẹẹ, ko ni pẹ o. Mi o le parọ fun yin, nigba ti wọn debẹ awọn eeyan sọ pe ara tu ilu, bi wọn ba ni ara tu ilu, ki i ṣe igba ti wọn ba lo ọdun marun-un tabi mẹwaa,, ki wọn to mọ.

Ẹni to kuro nibẹ ijọba oloogun lo n ṣe, o kan wọ agbada ni. Bi baba wa Bọla Ahmed Tinubu ba ti ifẹ awọn ọmọ orileede yii lọkan, wọn yoo ṣe ọdun mẹjọ, bi wọn ko ba ti ni, wọn ko le pari ọdun mẹrin-in, ẹ kọ silẹ,emi ni mo sọ bẹẹ, akanda ni mi, mi o kii ṣeeyan lasan.

Pẹlu akọsilẹ Tinubu, to ti ṣe fawọn araalu daadaa, mo ri i pe wọn laju ju eyi to kuro nibẹ yii lọ, iyẹn ko ni ọlaju rara. Amọran mi fun wọn ni pe ki wọn jẹ kawọn mẹkunnu gbadun ijọba wọn, ki wọn ko awọn ọdọ mọra, nitori awọn ọdọ akoko yii, ọpọlọ wọn pe o.

Ki  ṣe dandan ko jẹ awọn arugbo ti wọn ti n ṣe ijọba tipẹ, ni wọn yoo fi ṣe minisita,  ẹ le yan awọn to wulo ninu wọn, ki ẹ waa mu awọn ọdọ, ki ẹ fi kun wọn. Tabi ki ẹ fi awọn arugbo ti wọn ti mọ nipa iṣẹ naa ṣe akọkọ, ki ẹ fi awọn ọdọ se igbakeji wọn.

Nitori ti aarẹ ba kuna lati le gba mẹkunnu ninu ijọba ẹ, o tan, nitori idi eyi, Ọlọrun ti fẹ ko debẹ, eeyan le maa sọrọ, o le wa nile ẹjọ, ti Ọlọrun ko ba fẹẹ ki wọn debẹ, wọn ko nii ṣebura fun wọn. Ọlọrun to mu yin debẹ pẹlu awọnakitiyan yin,ta a ma n ri, ki ẹ wa lo lati fi gba ilu yii silẹ, ko si nnkan to buru tawọn oṣiṣẹ to kere ju ba n gba ẹgbẹrun lọna igba naira. Nitori ọwọngogo epo pẹtiroolu.

Owo sọbsidi ti wọn yọ yii, yoo jẹ ka ni owo lọwọ, mo waa fẹ ki wọn lo owo naa lati fi mu idagbasoke ba orileede yii. Bi ẹ ba ni emi naa fẹẹ sin orileeede yii, ebi ko pa mi, mi o tọrọ ounjẹ, idagbasoke orileede yii ta n sọ nipa ẹ.

Mo tun wa fẹẹ sin ilu yii laigba owo,aarẹ orileede yii ni mo lọ fun tẹlẹ, mo tun sọ nigba ti Oluwa ba mi sọrọ nigba kan pe ko ti ọ lẹyin.

Bawo ni ẹ ṣe ri eto aabo orileede yii si

Gẹgẹ bi mo tun ṣe jẹ igbakeji ọga fijilante nipinlẹ Ogun, iipnlẹ yii ni mo ti n ri oriṣiriṣi ajalu, bi eyi ko ba ṣe ogun owo, yoo lọ fọle, tabi ki wọn ji eeyan gba, wọn si n ribo kan sapamọ si, ki wa ni Gomina wa n ṣe, ti ko fi ri nnkankan ṣe, o difa pe ki i ṣe gbogbo nnkan leeyan mọ o, awọn ibikan wa ti o mọ iṣẹ de, waa pe awọn ọjọgbọn to mọ nipa ẹ.

Gba awọn to ba mọ pe wọn ni iriri ẹ, ko si kilọ fun wọn pe ti wọn ba kuna lati ṣe bo ṣe yẹ, waa yọ wọn. Ko sẹni to fẹẹ fiṣẹ silẹ, tabi ta ni ko fẹẹ rowo jẹun mọ, wọn a mu ni pataki.

Bi ẹ ba gbọ pe wọn huwa aitọ nipa eto aabo, ohun to tumọ si ni pe awọn ti wọn fi ṣe olori wọn ko kaju ẹ. Ọna abayọ ni pe awọn ọlọpaa ta a ni ko to,o yẹ ki a gba awọn alaabo agbegbe.

 

 


No comments:

Post a Comment

Pages