Kọmureedi Kennedy Iyere, to jẹ oludasilẹ ẹgbẹ kan ti wọn pe ni ‘’40 million Ballots Movements’’ ti sọ pe gbogbo eto lo ti fẹẹ to fun apero itaniji lẹyin idibo,ti wọn fẹẹ ṣe laipẹ yii niluu Owerri.
O sọ pe ipade yii ṣe pataki fun wọn lati le ṣagbeyẹwo ati atunto nnkan to ba yẹ lori ibo to waye ati lati jumọ wa irẹpọ ki wọn si le maa fimọ sọkan. Ọkunrn yii sọrọ ọhun nibi ipade oniroyin ti wọn pe, eyi to waye niluu Eko.
Kennedy tun fikun ọrọ ẹ pe apero ti yoo waye ọhun ni yoo pa gbogbo ẹlẹgbẹjẹgbẹ ati alakoso ‘’Obidients Movement’’ yii papọ. O sọ pe ọkan lara aṣeyọri pataki ti ẹgbẹ ọhun ti ṣe ninu eto oṣelu ilẹ wa to ti wa ninu akọsilẹ ti ko le parẹ ni bawọn ọdọ atawọn obinrin nipa ẹgbẹ yii ṣe jẹwọ ara wọn faraaye awọn lagbara lati ṣe ijọba, lati kopa, nitori awọn lo tọ si.
O ni bi ere ni wọn kọkọ pe ọrọ ọhun nigba tawọn ṣefilọlẹ ẹgbẹ ọhun tawọn kan roo pe ko le ṣee ṣe laimọ pe iṣẹ ti Ọlọrun ti pari ni. Oludasilẹ ẹgbẹ ‘’40 million Ballots Movements’’ tun sọ pe ibo to waye naa ti fihan daju pe ibo orileede yii ti kọja okoowo.
Iyere tun ṣalaye siwaju pe, ‘’ Ipade itaniji ti awa ẹgbẹ ‘’40 million Ballots Movements’’ fẹẹ ṣe ta a pe ni itaniji apero lẹyin ibo Obidient Movement, ni yoo faye gba awọn atunto awọn olori ẹgbẹ, ti yoo si so gbogbo wa pọ, emi Kọmuuredi Kennedy Iyere, lo ṣagbatẹtẹru ẹ’’
O sọ pe nibi ipade apero ti yo waye ọhun lawọn yoo tun ti wa abayọ lori bi awọn ọdọ atawọn obinrin yoo ṣe tubọ maa kopa ninu oṣelu, ti wọn yoo si maa ri ipo gidi di mu nibẹ.
O tun ni awọn yoo lo anfanii yii lati rii pe Obidient Movement, yan awọn aṣoju kaakiri ipinlẹ mẹrindinlogoji to wa lorileede yii, to fi de ilu Abuja, ti wọn yoo si ni aṣaaju bẹẹ lo ni gbogbo awọn ẹkun atawọn ara igberiko ni yoo kopa nibẹ.
No comments:
Post a Comment