Ọtunba Joel Ọlaniyi Ọyatoye, to jẹ aarẹ ajo Aṣa Day lagbaaye, eyi ti won n pe ni Asa Day Worldwide Inc., ti sọ pe iwa ọmọ Yoruba to jẹ ọmọluabi lo maa n jẹ ki a di ẹni itẹwọgba kaakiri ibi gbogbo ta a ba de lorile-ede, nitori ibi teeyan ba de ni aṣa ẹ yoo ba a de.
Ọkunrin naa sọrọ yii lakooko to n ba ẹgbẹ akọroyin ni ede Yoruba iyẹn Guild of Yoruba Media Practitioners (GYMP) fọrọ jomitoro ọrọ ni alẹ ana lati ile Canada. O ni gbogbo ibi ta a ba de ni wọn ti gbọdọ fẹ wa, nitori ojulowo iwa ọmọluabi ti wọn ri ninu wa.
O ṣalaye pe aṣa yii; oun fẹẹ mọ on si, idi niyi to fi jẹ pe titi di akoko yii loun ṣi n kẹkọọ ati pe awọn nnkan toto wa lawujọ wa lati jẹ ki a tubọ gbilẹ daadaa si ninu ẹ. Bẹẹ lo sọ pe ẹdun ọkan lo jẹ foun bawọn aṣiwaju gan-an nilẹ Yoruba ko ṣe mu igbelarugẹ si ede ati aṣa wa.
O waa gba awọn oniroyin ede Yoruba ọhun nimọran pe awọn ni wọn le gba ara wọn kalẹ ti wọn ba fẹẹ jẹ ki aṣa ati ede Yoruba tubọ gbilẹ si i nipa kiko ara wọn jọ lọ sileeṣẹ ajọ iṣọkan agbaye, iyen UN lati fi ẹhọnu wọn han lori oju tawọn aṣiwaju wa ṣe n wo ede wa, ti wọn ko si bikita.
O ni ti wọn ba le ṣe eleyii, itiju nla ni yoo jẹ fawọn naa, nitori bawo ni ede abinibi ṣe le wa ku, ti wọn yoo si maa wo o niran. Bẹẹ lo sọ pe ọpọ lo fẹẹ ba wọn ṣe, ti asọye ba si ti jọ wa, wọn yoo se ati pe nitori Ọlọrun ran oun lọwọ lo jẹ ki oun tete dide.
Bakan ni Ọyatoye tun mẹnuba ayajọ aṣa day ti ọdun yii, eyi to sọ pe orile-ede mẹta ni yoo ti waye, iyẹn lorile-ede Naijiria ninu oṣu kefa, London, ni ipari oṣu keje ati Canada ninu oṣu kẹsan-an, ohun to yoo si jẹ akori wọn fun ayajọ ọhun ni ‘’Ipa ti aṣa n ko ninu idagbasoke ọrọ aje’’ O ni ibẹ ni wọn yoo ti maa mu aṣa nikọọkan, eyi to le mu ọrọ aje wa.
O waa tan imọlẹ si i pe ọpọ eto toun ṣe lo jẹ pe owo ati isura ara oun loun maa n na le lori, fun apẹẹrẹ eyi ti wọn ṣe ni Eko, o ni wọn ṣeleri fawọn pe gbogbo owo tawọn na, lawọn yoo da pada amọ, to jẹ pe titi di akoko yii, awọn ko ri nnkankan.
Ọpọ lo si jẹ pe gbese loun maa jẹ lati fi ṣe ayeye ojo aṣa ọhun. Pupọ ninu awọn oṣere tawọn ba gbe wa si Canada ni ki i san awọn, kaka bẹẹ owo ni wọn yoo tun maa le kaakiri, ati pe awọn kan ṣe nnakn wọnyi lati fi fun awọn eeyan ni oore ọfẹ iṣẹnmbaye iyẹn museun tawọn ni, ki wọn le wa maa wo awọn nnkan to wa nibẹ ati pe awọn ki i gba owo, ọfẹ ni.
O waa pari ọrọ ẹ lori afojusun ẹ lati ri i pe ajo asa day da a duro lọjọ iwaju, to yoo le fa ajọ mi-in soke.
No comments:
Post a Comment