Awọn tọọgi kọlu Ọba Ara olorin ẹmi - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 30 April 2023

Awọn tọọgi kọlu Ọba Ara olorin ẹmiOri lo ko gbajumọ olorin ẹmi nni Dokita Oluwarotimi Ayinde Onimọle, tawọn eeyan tun mọ si Ọba Ara, ni ana, ọjọ Abamẹta, Satide, nigba tawọn tọọgi lọ kọlu nibi to ti n ṣere, ti wọn si ba bọọsi ẹ jẹ.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ, nibi ayẹyẹ kan ti wọn ṣe ni ọgba ileewe High School Campus, to wa ni Ifẹtẹdo, nipinlẹ Ọṣun, ni gbajumọ olorin gọsipẹli, to tun kọ Juju ati Fuji iyẹn JuFujiGospel, ti lọ ṣere fun wọn,

Iwadii fi ye wa pe loju ẹsẹ ti Ọba ilu naa, to tun jẹ agbẹjọro, Ọba Akinọla Akinrere Latiri 1, Olubọsin ilẹ Ifẹtẹdo, kuro loju agbo naa ni wọn sọ pe awọn janduku yii debẹ.

Ninu ọrọ Ọba Ara, lo ti sọ pe’’ Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun pe ko si ẹni to farapa ninu awọn ọmọọṣẹ mi ta a jọ lọ,ṣe ni wọn kọlu wa gidi gn-an ni. Bi emi ṣe ri i pe wọn n bọ ni mo ti sare fun wọn lowo pẹlu owo nla, sibẹ naa wọn tun kọlu wa, ti wọn si ba mọto wa jẹ’’

O tun sọ pẹlu iyalẹnu pe awọn eeyan naa ko ni ibẹru Ọlọrun o, eeyan buruku ni wọn, ti wọn si buru gan-an ni. O ni loju ẹsẹ ti wọn raye sa lọ mọ wọn lọwọ lawọn gba ọdọ Kabiyesi ilu naa lọ, lati lọ fiṣẹlẹ ọhun to wọn leti.

Ọba yii lo ni o waa ran awọn lọwọ to pe awọn ọlọpaa ti wọn si mu ọkan lara awọn tọọgi naa, pẹlu ileri pe ọwọ yoo tẹ awọn yooku laipẹ yii. O waa lo akoko naa lati fi dupẹ lọwọ Kabiyesi naa fun ifẹ to fihan si awọn, to si huwa gẹgẹ bi baba si wọn pẹlu.

No comments:

Post a Comment

Pages