Orileede yii ko gbọdọ ju annfani iṣejọba rere nu- Wolii Gẹnesis - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 3 February 2023

Orileede yii ko gbọdọ ju annfani iṣejọba rere nu- Wolii GẹnesisWolii Isreal Ogundipẹ, tijọ ṣọọṣi Genesis, ti rọ gbogbo ọmọ orileede yii lati lo anfaani ibo to n bọ yii lati fi yan aṣaaju rere. O sọrọ  naa nibi iṣẹ to ran Gbọlahan Aṣhorobi, nigba to dawọn lẹkọọ lori akori kan to pe ni Ipa ti ẹsin n ko lati fi tun awujọ ṣe, nibi eto ẹgbẹ awọn oniroyin lori ẹrọ ayelujara iyẹn Online Reporters Association of Nigeria, ORAN, ṣe ni ootẹli Oriental,  Victoria Island, niluu Eko.

 

Lara awọn to tun sọrọ nibẹ ni Ọmọọba-binrin Fọlaṣade Ọlabanji, to jẹ igbakeji ijọba ibilẹ Ikorodu, o gba awọn ọdọ orileede yii nimọran lati ji dide, ki wọn si sa agbara wọn lati le jẹ ki Naijiria tun goke agba.

 

 O rọ wọn lati gbagbe ọrọ kan ti wọn maa n sọ pe awọn ọdọ lo ni ọjọ ọla, o ni ki wọn ma duro de ọjọ ọla, ki wọn bẹrẹ lonii, ki wọn si sa agbara wọn lati le mu ayipada rere wa.

 

O ni ọdọ ko le jẹ ọjọ ọla bi ko ṣe aṣaaju ọjọ oni.Bẹẹ lo ni ki wọn sa fun gboghbo awọn nnkan to le maa da wahala silẹ, ki wọn si maa ṣa ipa wọn nigba gbogbo. Ninu ọrọ Ọnarebu Akinwumi Baithwaite, to jẹ oludije gomina fẹgbẹ oṣelu National Rescue Movement, NRM, nipinlẹ Eko, nibi eto naa, lo ti sọ pe awọn ọmọ orileede yii gbọdọ ji dide ninu oorun wọn, ki wọn si wo ẹyin wo, fun ti ibo gbogbogboo to n bọ lọna yii.

 

O sọ pe pataki iṣejọba rere ni ki awọn ọmọ orileede yii dibo fẹni ti ọkan wọn ba sọ pe wọn yoo ri anfaani ninu ẹ.

 

 O sọ pe awọn oniroyin paapaa julọ awọn ayelujara ni lati ran awujọ yii lọwọ, bẹẹ lo ni ki wọn rii pe wọn ṣe iwadii lori awọn iṣẹ iroyin wọn.

 

Ọnarebu Akinwunmi Braithwaite , Ọnarebu Fọlaṣade Ọlabanji ,ati Wolii Israel Ogundipẹ, ti Ọgbẹni Gbọlahan Ashorobi, ṣoju fun ni wọn gba ami ẹyọ lori awọn ipa ti wọn ti ko lori idagbasoke awujọ.


No comments:

Post a Comment

Pages