Biyi tun ti gbẹyẹ mọ awọn ọlọtẹ ẹ lọwọ ni kotẹmilọrun lonii, ni APC ba lulẹ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 3 February 2023

Biyi tun ti gbẹyẹ mọ awọn ọlọtẹ ẹ lọwọ ni kotẹmilọrun lonii, ni APC ba lulẹ 

Idunnu lo tun subu layọ Agbẹjọro Biyi Ọtẹgbẹyẹ, oludije gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC, lonii, nigba to tun gba idalare nile ẹjọ kotẹmilọrun, to wa niluu Ibadan, nigba ti ẹgbẹ oṣelu APC, fidi jablẹ patapata.

 

 Ninu idajọ ẹjọ ti nọmba ẹ jẹ CA/IB/560/2022, to waye ọhun ni Adajọ ti sọ pe oludije  to kopa nibi ibo abẹle ninu ẹgbẹ naa lo lẹtọọ lati pẹjọ to ba ri nnkan to ruu loju ki i ṣe awọn ti ko si ninu wọn.

 

Bẹẹ lo ni alatako oloṣelu ko niṣẹ kankan ṣe lat pe ẹni ti wọn ko jọ si ninu ẹgbẹ kan naa lẹjọ. O waa paṣẹ pe ki APC san ẹgbẹrun lọna igba le aadọta Naira (250,000,00) fun Ọtẹgbẹyẹ lori pe wọn gbe e lẹmi gbona.

 

A o ranti pe lọsẹ to kọja ni Ọtẹgbẹyẹ ti kọkọ jawe olubori ninu ẹjọ kotẹmilọrun ti ẹgbẹ oṣelu Labour pe to waye niluu Ibadan, pẹlu bo tun ṣe wa ṣẹlẹ lonii, o ti wa di ẹẹmeji ọtọọtọ ti Biyi fi gba ẹyẹ mọ awọn ọlọtẹ lọwọ.

 

Gbogbo ete Gomina Dapọ Abiọdun lati da a oludije gomina ADC lọwọ duro lati ma ṣe kopa lo ti wa jo si pabo to ti waa lulẹ patapata bayii.

 


No comments:

Post a Comment

Pages