Ọlọrun ma jẹ, Ogun West ko tun jiya wọ ọdun 2027- Ọtẹgbẹyẹ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 5 February 2023

Ọlọrun ma jẹ, Ogun West ko tun jiya wọ ọdun 2027- Ọtẹgbẹyẹ 

Agbẹjọro Biyi Ọtẹgbẹyẹ, oludije gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress (ADC), nipinlẹ Ogun, ninu ibo to n bọ ni oṣu kẹta ọdun yii  ti sọ pe ki awọn kan ma ṣe fi bọta ko wọn ni ọbẹ jẹ awọn eeyan Ogun West, ko nii bawọn duro mọ di ọdun 2027, ko to di pe wọn di gomina.

 

Ọja ọdan ni o ti sọrọ ọhun nigba to gbe ipolongo ẹ de ijọba ibilẹYewa North, o sọ pe gbogbo isọkusọ tawọn kan  n sọ pe ki wọn duro de ọdun naa, ki i ero tawọn eeyan Yewa Awori.

 

O waa beere lọwọ awọn eeyan ọhun pe igba wo ni ẹ fẹẹ fo gomina lakooko yii ni abi ọdun 2027, ko si tii sọrọ naa delẹ ti gbogbo wọn fi pariwo pe akoko yii lawọn n fẹ.

 

Ọtẹgbẹyẹ tun ṣalaye pe, Gbogbo igba ni mo maa n sọ pe akoko ti to fun Ogun West, lati ni gomina. Ẹdun ọkan lo jẹ pe lati ọdun 1976, ti wọn ti da ipinlẹ naa silẹ, gbogbo awọn ẹya yooku ni wọn ti mọ adun aṣaaju ṣugbọn awa nikan ni a ko tii ni.’’

 

‘’Mo fẹẹ ki ẹ mọ pe akoko ti to fun wa bayii, fun anfaani gbogbo wa ni ọtẹ yii, ko si iyapa laarin wa, oludije kan ṣoṣo lo wa lati ẹkun wa nibi, to n dije fun ipo gomina’’.

 

‘’ Ni apa ẹkun mii nipinlẹ Ogun, awọn ti wọn jade ti wọn jọ dije pọ laarin wọn, ṣugbọn ni Ogun West, mo mu dawọn eeyan mi loju pe ẹgbẹ oṣelu ADC ni wọn yoo dibo fun, gẹgẹ bi gomina  ninu ibo to n bọ ọhun, ni agbara Ọlọrun ko si nnkan to le yipada’’

 

O waa sọ pe awọn eeyan oun ti muu da oun loju pe wọn yoo fi ibo wọn gbe oun wọle gẹgẹ bi gomina.


No comments:

Post a Comment

Pages