Ki Asiwaju Bola Ahmed Tinubu di aare orileede yii je wa logun - ADC Ogun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday 21 February 2023

Ki Asiwaju Bola Ahmed Tinubu di aare orileede yii je wa logun - ADC Ogun




 Egbe oselu ADC nipinle Ogun, ti so pe idunnu awon ni ti Asiwaju Bola Ahmed Tinubu, ba di aare orileede yii ninu Ibo ti yoo waye lojo Satide, ose yii.

Ninu atejade ti alaga egbe naa,Adelanwa Matemilola fowo si lati fi tako aheso oro kan tawon kan gbe jade pe egbe naa lapapo ti gba lati sise Po fun Peter Obi, ti egbe Labour.

Alaga naa so pe ko si nnkan to jo ati pe tokantokan ati ara lawon fi n sise po pe ki Tinubu di aare ninu Ibo to n bo naa.

O fikun oro e pe gege bi awon se so nita gbangba lakooko ibere ipolongo won ninu osu yii pe ti Tinubu lawon n se, o mi bee naa lo si wa, ti ko le yipada.

O ni awon lo akoko naa lati fi dari gbogbo omo egbe naa nipinle Ogun atawon alatileyin won, ki won ma se tele aheso kankan,Tinubu ni ki won dibo won fun.


O waa so pe awon si wa lori oro won lati fi tun ipinle Ogun se lona tawon araalu yoo fi je anfaani e.


No comments:

Post a Comment

Pages