E fi oruko awon oludije asofin wa si iwe Ibo ojo Satide tabi-Alaga egbe oselu Labour. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 23 February 2023

E fi oruko awon oludije asofin wa si iwe Ibo ojo Satide tabi-Alaga egbe oselu Labour.



Alaga fegbe oselu Labour nipinle Eko, Pasito Dayo Ekong, ti ajo eleto idibo lorileede yii iyen INEC, lati fi oruko awon oludije asofin won sinu iwe Ibo ti yoo waye ni otunla, Satide yii tabi ki won sun Ibo won siwaju.

Ninu atejade ti Iyaafin Bunmi Odesanya, to je olupologo egbe naa fowo si loruko alaga won nibi ipade oniroyin to waye lonii ni ofiisi egbe naa niluu Eko. O so pe oun gbo firifiri pe oruko awon oludije asofin naa iyen asoju-sofin ati asofin agba ko si ninu iwe Ibo ti won fee di naa.

Alaga naa so pe ki ajo eleto idibo lorileede yii tete se atunse le e lori lo to di pe Ibo yii yoo waye.

O salaye siwaju pe, "Iyalenu lo je fun wa pe Ibo ti yoo waye lojo Satide ose yii, ti aare nikan ni ajo eleto idibo INEC, faye sile fun un nigba ti ko si oruko awon oludije asofin wa to ye ki wa nibe lati ipinle Eko, ko si nibe"

O ni awon ko le gba iru e, nitori awon lo nigbagbo pe ajo eleto idibo naa si asise. O bigba pe won mo on mo huwa naa lati fi ko irewesi ba awon omo egbe oselu naa ni. Eyi to ni awon ko le se atewogba e.

Dayo Ekong, waa fikun oro e pe ayewo tawon se lori ero alatagba iyen website je kawon mo pe pelu bi ase Ile ejo se so pe ki won foruko awon oludije asofin agba ati asoju sofin si, sibe won ko pa a mo, pelu bi won se gba iwe ejo naa.

O ni  a o ranti bi awon ti se n ke gbajare sita lori bi ajo eleto idibo lorileede yii iyen INEC se n soju saaju paapaa julo oga won to wa nipinle Eko, to si fojoojumo doju ija egbe oselu Labour.

Ni bayii, won ti wa ke si INEC, lati tete wa atunse ko to di ojo Ibo nitori awon setan lati gbe igbese ofin bi won ba ko.

No comments:

Post a Comment

Pages