Wọn fun Ibrahim Dende Egungbohun ni awọọdu Ògidì- Ọmọ ilẹ Yoruba - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 15 January 2023

Wọn fun Ibrahim Dende Egungbohun ni awọọdu Ògidì- Ọmọ ilẹ Yoruba



Idunnu ṣubu layọ lọsẹ to kọja, nigba ti wọn fun Alaaji Ibrahim Dende Egungbohun, tọpọ awọn eeyan mọ si IBD, ni awọọdu Ògidì-Ọmọ, tawọn oloyinbo n pe ni Golden Son, fun gbogbo ilẹ Yoruba.

 

Ayẹyẹ ọhun to waye lọjọ Iṣẹgun Tusidee, ni ọfiisi ọkunrin naa to wa niluu Ilaro, lawọn eeyan ti gboṣuba fun-un, ti wọn si n sọ pe loootọ ni awọọdun ọhun yẹ e, ko si si nnkan mii-in bi ko ṣe awọn akitiyan ẹ lati mu inu awọn eeyan dun, ati idagbasoke to mu ba ilẹ Yoruba gbogbo.

 

Akinwale Ọlanrewaju, to jẹ alaga awọn oniroyin nipinlẹ Ogun, lo gbe awọọdu ọhun lee lọwọ lọjọ naa lorukọ ileeṣẹ FAJ Communication, eyi ti Ọgbẹni Abiọdun Oluwafẹmi jẹ adari ẹ, gbe fun ilu mọ-ọn- ka ọkunrin naa

 

Ninu ọrọ alaga fawọn oniroyin lọjọ naa, lo ti ki IBD, ku oriire awọọdu ọhun to si rọ ọ lati tẹsiwaju ninu bo ṣe n gbe awọn eeyan dide, ti ko si fi ti ẹya kankan ṣe.

 

O ni ‘’Egbon a  gbo, bi ẹ ṣe maa n ran awọn eeyan lọwọ paapaa awọn elere Idaraya ati awọn elere ori-itage to fi mọ awọn olorin lọwọ bẹẹ la si n fẹ ki ẹ tan imọle ẹ de ọdọ awa oniroyin naa, a si gbadura pe Ọlọrun ọba yoo maa ran ẹyin naa lọwọ, yio si maa wa pẹlu yin nigba gbogbo’’

 

 

Nigba ti oun naa sọrọ, Ọgbẹni Abiọdun Oluwafẹmi, Oludasile Ileeṣẹ FAJ Communications, to n gbe iwe iroyin AKAJERE, Iroyin YEWA ati FAJISTV  jade, dupẹ lọwọ, alami ẹyẹ naa, to tun jẹ oludasilẹ Ileetura IBD, fun atilẹyin rẹ latigba to ti da ileeṣẹ iroyin ẹ silẹ.

 

O ni awọọdu ti IBD gba yii lawọn fun un lakooko ayẹyẹ ajọdun ọdun karun-un ti wọn da iwe Iroyin Yewa silẹ, tawon si ṣe ikowojọ fun Ileeṣe redio, Iroyin Yewa lọdun 2021, ṣugbọn ti ko le wa lọjọ naa.

 

O tẹsiwaju ninu ọrọ ẹ pe ohun to tun jẹ ki awọọdu yii pẹ to fi di ọjọ ti wọn ṣe yii ni ti alaga awon oniroyin to di oloogbe nigba naa iyẹn Sọji Amosu, nitori oun lo ti fẹẹ gbe awọọdu yii fun wọn amọ ti iku ko jẹ.

 

Idi niyii toun fi da aduro titi digba ti wn fi yan alaga tuntun mii-in, to si tun jẹ ọmọ Yewa. O waa rọ Ibrahim Dende, pe ko ma ṣe dawọ atilẹyin ẹ duro, ko si tete mu awọn ileri to ṣe fun ileeṣẹ FAJ Communications ṣẹ.

 

Nigba to n dupẹ fun ti awọọdu nla ti wọn fun un na, Alaaji Ibrahim Dende, fi ẹmi imoore ẹ han fun FAJ Communications, fun apọnle nla ti wnọn ṣe fun ọhun, o wa ṣeleri pe oun yoo maa sa gbogbo ipa oun lati fi ran ileesẹ naa atawọn mii-in to jẹ akọroyin lọwọ. Bẹẹ lo tun rọ wọn ki wọn maa fi otito ṣiṣẹ wọn, ki wọn ma maa gbe si Ibikan

No comments:

Post a Comment

Pages