Ẹgbẹ MAAN yan awọn oloye tuntun bẹẹ ni wọn tun da awọn kan duro - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 13 January 2023

Ẹgbẹ MAAN yan awọn oloye tuntun bẹẹ ni wọn tun da awọn kan duroẸgbẹ awọn to n gbe olorin jade lorileede yii, Music Advertisement Association of Nigeria, MAAN, ti yan awọn oloye fidiẹ tuntun, ti wọn yoo maa ṣakoso ẹgbẹ naa fun odidi oṣu mẹrin, ti wọn yoo fi ṣeto ibo laarin wọn.

 

Nibi ipade ẹgbẹ ọhun to waye ni ọfiisi wọn niluu Eko, ni wọn ti yan awọn oloye fidihẹ ọhun bẹẹ ni wọn tun da awọn kan duro fun igba diẹ, nitori aṣiṣe ti wọn ṣe, ti wọn fẹẹ fi maa ba ẹgbẹ naa loju jẹ. 

Awọn oloye fidiẹ tuntun ọhun ni Ọgbẹni Iyiọla, to jẹ alaga wọn, Ọgbẹni Jamiu Bakare, toun jẹ akọwe, Ọgbẹni Shuaib Adewuyi, Ọgbẹni Ahmed Aṣiwaju, Ọgbẹni Adeyẹmi Julius, Ọgbẹni Ori Apesin,ati Ọgbẹni Falọmọ.

 

Alaaji Akeem Ogunwale, to ti figba kan jẹ aarẹ ẹgbẹ naa lo bura fawọn oloye ọhun, ti wọn si rọ wọn lati bẹrẹ iṣẹ loju ẹsẹ, oṣo mẹrin si ni wọn yoo fi wakọ ẹgbẹ yii, ti wọn yoo fi ṣeto awọn oloye tuntun.

 

Awọn ọmọ ẹgbẹ wọn ti wọn da a duro ni Taiwo Fatoyebo. Arigbabuwo 

Musibau, Alubarika Giwa, Surajudeen Amusa

ati Alapanla.

  Ninu ọrọ Alaaji Waheed  Oyediran, tọpọ mọ si Moṣebọlatan, nigba to n tan imọlẹ si ọrọ naa, o sọ pe awọn tawọn pe lẹjọ fun aṣemaṣe ti wọn ṣe, awọn fi wọn silẹ fun ẹjọ to wa nilẹ ọhun,amọ awọn ti wọn darukọ wọnyii pe wọn da a duro ni wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ ti wọn lẹ da ọwọ hu, lẹyin ti kootu ti sọ pe awọn ko gbọdọ ṣeto ibo kankan, amọ ti wọn ko bọwọ fun ofin ile- ẹjọ.

 Lara awọn to wa nibi ipade wọn ọjọ naa ni Alaaji Baṣiru Bankọle, to jẹ alaga igbimọ awọn agba fẹgbẹ naa,Alaaji Sulaimon Amingo.

No comments:

Post a Comment

Pages