Sẹnetọ Adeola ṣeleri miliọnu lọna aadọta Naira lati fi pari iṣẹ akanṣe ina ni Ketu - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 29 January 2023

Sẹnetọ Adeola ṣeleri miliọnu lọna aadọta Naira lati fi pari iṣẹ akanṣe ina ni Ketu



Sẹnetọ Sọlomon Ọlamilekan Adeọla, to n dije fun ipo aṣofin fun ẹkun Ogun West, labẹ ẹgbẹ oṣelu APC,ninu ibo to n bọ yii, ti muu dawọn eeyan Ketu, nijọba ibilẹ Yewa North, nipinlẹ Ogun loju pe iṣẹ akanṣe ina ti banki agbaye fi ran awọn igberiko lọwọ, ti wọn ṣe pati, ti yoo maa fawọn agbegbe mẹtadinlọgọta ni ina ti owo ẹ to miliọnu lọna aadọta naira, loun yoo bawọn pari laipẹ.

 

Aṣofin naa ṣeleri yii lakooko lo gbe ipolongo wọọdu si wọọdu to n ṣe kaakiri ẹkun Ogun West, de Yewa North, nibi to ti mu irinajo ẹ de awọn agbegbe bii Ebute, Ọja-Ọdan, Ohunbẹ, Igbeme, Tata, Eggua, Igan-Alade, Owode-Ketu ati Ijoun. 

 

Adeọla sọ pe, “Ẹdun ọkan lo jẹ fun mi pe iṣẹ akanṣe wa, ti banki agbaye n ṣe lati fi ran awọn igberiko lọwọ fun ina, ti wọn ti ba a de ida aadọrun, ki wọn pari ẹ, amọ ti wọn ti pati, nitori iṣoro owo ti wọn yoo fi pari ẹ.  Pẹlu awọn nnkan ti mo n gbọ, o wu mi ki n ri ipari iṣẹ akanṣe naa, eyi tawọn agbegbe mẹtadinlọgọta yoo jẹ anfaani ẹ. O si da mi loju pe bi wọn ba le pari ina ọhun yoo tun jẹ ki eto ọrọ aje ati idagbasoku tun lọ si oke lawọn agbegbe naa’’

 

 

Bẹẹ lo tun sọ pe oun fẹẹ ki wọn tun lọ oun lọyẹ si nipa iṣẹ akanṣe naa, ni eyi ti yoo mu ki oun tete fi owo silẹ lati fi tete pari ẹ. O ni to ba jẹ pe miliọnu lọna aadọta ni wọn yoo fi pari iṣẹ naa, ki wọn sọrọ soke, nitori eyi tawọn toun fẹẹ lọ ṣoju fun fi n foriti ti to gẹ.

 

Bakan naa lọjọ naa ni Sẹnetọ Adeọla tun fawọn iya lọja ni Ọja Ọdan ni miliọnu marun-un naira lati fi pari ibi itọju agbado si, ti yoo maa gba irinwo baagi, miliọnu marun-un naira mii-in lo fun wọn fun ti afin Ọba  Basiru Oyero, Onijalẹ ti Ijalẹ Ketu, bẹẹ lo tun fawọn Ohunbẹ, Ọja-Ọdan, Igan-Alade ati Ijoun  ni tiransifọma tuntun.

 

Sẹnetọ tun wa ṣeleri lati bawọn pari teṣan ọlọpaa ti wọn n kọ lọwọ si Eggua ati Ijoun, ti yoo si tun ba wọn kọ kilaasi oniyara mẹjọ, ọfiisi ati ile iyagbẹ si ileewe alakọbẹrẹ Yewa North Primary School, ni Ijoun. 

 

Lọjọ naa tun ni Senato Adeọ tun dẹrin pa ẹẹkẹ awọn iyalọja ẹgbẹrun marun un ati awọn ọdọ ẹgbẹrun marun-un,  nipa riro wọn lagbara atawọn abarapa igba, to fawọn yẹn ni ẹgbẹrun lọna igba naira lati bẹrẹ okoowo.

 

Ko to to akoko yii ni ọja Ọja-Ọdan, nibi tawọn ọpọlọpọ awọn eeyan ti pejọ lati ki Sẹnatọ Adeola, kaabọ, ni Ọnarebu Job Akintan, to ti figba kan jẹ ọmọ ile igbmọ aṣofin nipinlẹ Ogun, ti kọkọ mẹnuba iṣẹ akanṣe akọpati ina ọhun, ti yoo na wọn to miliọnu lọna aadọta naira, ki wọn to pari ẹ.

 

 


No comments:

Post a Comment

Pages