Gbadebọ lawọn ko nii gba ki wọn ma lu ọmọ ẹgbẹ oṣelu Labour nilukulu - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 28 January 2023

Gbadebọ lawọn ko nii gba ki wọn ma lu ọmọ ẹgbẹ oṣelu Labour nilukulu



 

Bi ki i ba ṣe ọpẹlọpẹ Ọlọrun, o ku diẹ kawọn tọọgi oloṣelu kan ṣa ọkunrin kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Joseph Ọjagberovwe pa, lakooko to n lẹ posita oludije aarẹ ati gomina wọn.

 

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, lọjọ Aiku, Sannde, to kọja yii, ni wọn sọ pe awọn tọọgi oloṣelu ọhun digbo lu ọkunrin yii lagbegbe Peace  Estate,  Iba nijọba ibilẹ Ọjọ, nipinlẹ Eko.

 

Iwadii fi ye wa pe meje lawọn tọọgi naa ati pe bi wọn ṣe rii pe o lẹ posita, ti wọn si lọọ ba pe ki lo de to fi lẹ awọn posita ọhun, ti wọn si sọ fun un pe wọn  ko le jawe olubori, ko ye lẹ posita wọn mọ.

 

Ere ni wọn sọ pe Joseph pe ọrọ naa tẹlẹ a fi bi wọn ṣe ko igbaju igbmu bo, ti wọn ni ọkan ninu wọn fa ada yọ, to si gbe le e ni ori, ti ẹjẹ bẹrẹ si nii jade.

 

Lẹyin ti wọn da sẹria fun ọkunrin yii tan la gbọ pe wọn tun fa posita to ti lẹ ya, ti wọn si sa lọ. Ọpẹlọpẹ awọn to wa nitosi niwọn sare gbe ọkunrin naa lọ sile iwosan nibi to ti n gba itọju titi di akoko yii.

A gbọ pe loju ẹsẹ ni wọn ti lọ fọrọ naa to awọn ọlọpaa to wa ni Iba, leti. Wọn ni iyalẹnu lo jẹ pe titi di akoko yii awọn ọlọpaa naa ko gbe igbesẹ Kankan lee lori, pẹlu bi Joseph, ti wọn ṣe nijamba naa ṣe sọ pe oun dawọn tọọgi ọhun mọ.

Ni bayii, oludije gomina fẹgbẹ oṣelu Labour nipinlẹ Eko, Ọgbẹni Gbadebọ Rhodes- Vivour, ti wa ṣe ikilọ fawọn tọọgi oloṣelu to dunkoko mọ awọn ọmọ ẹgbẹ ẹ ki wọn fopin si nitori awọn ko nii ma wo wọn niran lati maa ṣe ijamba fawọn eeyan wọn.

O sọ pe gbogbo igbesẹ lawọn ti gbe de ọdọ awọn ọlọpaa lati ṣiṣẹ lori awọn ẹni ibi ọhun amọ ti wọn ko ṣe nnkankan le wọn lori, o ni o dabi ẹni pe wọn ti fẹẹ sun awọn mọ ogiri, ibikibi ti wọn ba tun ti fiya jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu Labour, awọn naa ṣetan lati gbija ara wọn.

Bakan naa lo rọ gbogbo awọn olugbe ipinlẹ Eko lati ri i pe wọn gba kaadi idibo wọn, nitori oun nikan ni olugbeja ti wọn le lo lati fi kopa ninu ibo ti yoo waye laipẹ yii.

 


No comments:

Post a Comment

Pages