Idajo kotemilorun, aseyori nla lo je fun omo ipinle Ogun-Otegbeye - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday 23 January 2023

Idajo kotemilorun, aseyori nla lo je fun omo ipinle Ogun-Otegbeye
Yoruba bo won ni Inu eni kii dun ki a pa mora, idi niyi ti Agbejoro Olubiyi Otegbeye, oludije gomina labe egbe oselu ADC, nipinle Ogun, fi so pe aseyori naa ki i se toun nikan bi ko se gbogbo awon omo ipinle naa.

Ninu atejade to fi sita leyin to jawe olubori lo ti so pe tokantokan ni Inu oun fi dun, nitori oun ko siyemeji tele latigba ti idajo fi waye,nitori gbogbo nnkan to ye kawon se labe ofin eto idibo lawon se lakooko idibo abele won.

O so pe awon dupe pe ebe won se itewogba nile ejo kotemilorun.O wa lo akoko naa lati fi gboriyin fun eka eto idajo wa lori bi won se je kawon araalu nireti ninu idajo

. Otegbeye so pe" O ti han gbangba pe egbe oselu APC to n sejoba ti padanu awon eto to ye lati le je ki araalu dibo yan won wole ni eleekeji, pelu owo ti won na lati fi fa oju awon eeyan mora nitori ibo".
 
O so pe o se ni laanu pe awon egbe oselu naa ti padanu,won si gbodo murasile lati mo bi won se to lori papa.

O tun so pe" Erongba wa fodun merin to n bo ni lati fi tun ipinle Ogun se, ki a si se atunse awon nnkan ti won ti baje. Ijoba ADC yoo pese anfaani  fawon eeyan lati le da ogo ipinle yii pada""

O waa so pe aseyori tawon se yii ki i se fun egbe won nikan bi ko se fun gbogbo eeyan ipinle Ogun ti won ti n foriti gbogbo inira ti APC mu bawon.

Otegbeye waa gba awon araalu lamoran lati gbaradi fun ibo to n bo naa nipa gbigba kaadi ibo alalope nni iyev PVC. Bee lo wa dupe lowo awon iyaloja,omoleewe, onise owo,elegbejegbe atawon to wa ni oke okun fun atileyin won nigba ti igbejo n lo lowo.

.

No comments:

Post a Comment

Pages