E so fun Dapo Abiodun pe Olongbo ti tajo de- Biyi Otegbeye - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 25 January 2023

E so fun Dapo Abiodun pe Olongbo ti tajo de- Biyi Otegbeye



Oludije Gomina labe egbe oselu ADC nipinle Ogun, Agbejoro Biyi Otegbeye, ti paroko ranse si Gomina Dapo Abiodun pe ko maa palemo eru e lati kuro nile ijoba ninu osu karun-un odun yii, nitori olongbo ti tajo de, ki ekute Ile paramo.

O soro yii lakooko to n ba awon oniroyin soro lana-an fun bo se jawe olubori ninu igbejo kotemilorun lorun to pe nibi ti egbe oselu APC ati Labour ti lule patapata.

O so pe pelu iranlowo Olorun ati atileyin Seneto Ibikunle Amosun, oun yoo feyin Gomina Dapo Abiodun gbole nibi ibo gimina ti yoo waye ninu osu keta odun yii.

Bakan naa lo so pe oun ko ri bi Gomina Abiodun se lo n bawon oba alaye kaakiri ipinle naa lati fowo si ipadabo eleekeji e to, nitori o da oun loju pe awon ti yoo fowo si gan-an ni won yoo yoju lojo idibo.

O fikun oro e pe ki Dapo Abiodun ye da ara e laamu mo ko je kawon pade lori papa iyen ojo tawon eeyan yoo fi ibo won gbe oun wole.

Otegbeye tun so pe " Oro e ko jo mi loju rara nitori bo se n lo kaakiri pe kawon eeyan dibo foun, ose meji leyin e mo sabewo lo sodo oba mi, o gba mi towo tese bee lo tun sure fun mi"

O ni ooto oro tawon Yoruba maa n so pe eje san ju omi lo,nitori ko si baba to le so pe oun yoo da omo oun nu.

Oludije Gomina naa so pe ki won je ki a wo boya fifowosi ti Dapo Abiodun n ba Kiri yoo to kika ibo lodo ajo eleto idibo INEC.

O tun salaye siwaju pe " Bi a ba ni ka se afiwe bo se n lo kaakiri fun itewogba ati ti Amosun, nibi to ti so nigbangba pe oun satileyin fun Biyi Otegbeye ati ADC.

Bee lo so pe oriire tawon se nile ejo kotemilorun ki i se tawon nikan bi ko se gbogbo awon eeyan ipinle Ogun.

Nitori Olorun ti so pe akoko to lati gba awon araalu kuro lowo bijoba to wa lode yii se n faraniwon.

O ni bo tile je pe igbejo kotemilorun naa mu ifaseyin ba eto egbe naa to si tun na won lowo sugbon awon dupe pe gbogbo e ko lo lasan.

O waa seleri pe ti won ba fi le dibo yan oun wole, ijoba oun yoo ri pe won satunse sawon nnkan tijoba to wa lode yii ti baje.

O waa pari oro nipa gbigba awon araalu lamoran lati loo gba kaadi idibo alalope won iyen PVC, ki won le fi le ijoba to wa lode yii kuro nipo.



No comments:

Post a Comment

Pages