Awon Oba Yewa gbadura nla fun Yayi, won ni leyin Seneto, Gomina lo kan - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday 31 January 2023

Awon Oba Yewa gbadura nla fun Yayi, won ni leyin Seneto, Gomina lo kanAwon Yoruba bo, won ni inu eni ki i dun ka pa a mora bee gele loro ri lonii fawon oba alaye kan nile Yewa ti won bere si nii rojo adura le Seneto Solomon Adeola, to n dije fun ipo seneto labe egbe oselu APC, fun ekun Ogun West.

Nibi ipolongo woodu si woodu ti Asofin naa n se to gbe de Yewa North, ni ojo adura ti n ro lee lori lati enu awon oba alade.

Adokun ti Igan Okoto, Oba Mukaila Akanbi Salako, lo koko bere adura maa fun aseyori Seneto Yayi, leyin naa lawon oba bii mewaa naa tun fi opa ase won sure fun un.

 Alaye  tiluu Ayetoro, Oba Abdullaziz Adelakun, fi idunnu e han si Seneto lori inawo nara e lori afin to ba won se. O so pe ka mu tegan kuro, Yayi ti jawe olubori ninu ibo naa nitori awon ise idagbasoke to ti se lati nnkan bi odun mewaa to ti sin awon eeyan bere lati Eko.

Oba naa so pe“ Awa oba alaye ko siyemeji lori ati wole ninu ibo to n bo naa. Adura waa ni pe leyin seneto yii o n bo wa di gomina nipinle Ogun. Ko si si nnkan mii-in bi ko se awon ise idagbasoke to ti mu ba awon agbegbe. Mo ranti ni nnkan bi odun meloo kan seyin to ran awon oba Yewa lo siluu Oyinbo ati bo se n fi nnkan ranse si wa a kere ju eemerin lodun,o da wa loju pe waa si di gomina lagbara Olorun ""

Ko to di pe awon oba alaye yii sadura ni 
Abepa ti Joga Orile, Oba Adeyemi Adekeye,  ti koko gboriyin fun Seneto Adeola, lori eto imayederun ati ironilagbara to se fawon eeyan, o ni eyi to se pataki ju nibe ni pe ko tesiwaju lati maa mu ileri to se fawon eeyan se.

 Ko to akoko yii ni Seneto Adeola ti so pe pataki idi toun fi loo sawon woodu call lati le mo ipenija tawon to n gbe nibe fojoojumo koju, eyi to ni oun yoo bere atunse lee lori loju ese ko di pe won dibo lojo keeedogbon, osu yii.

Lara e tiransifoma meeedogbon, titun awon ona se ati pipari tesan an olopaa,to ni yoo na oun ni aimoye milionu.

Bee lo ni ko to di akoko ibo oun yoo ro awon obinrin atawon odo lagbara.O waa ro awon eeyan naa lati dibo won fun gbogbo oludije egbe APC ninu ibo to n bo yii.

Bakan lo tun seleri pe won yoo tun ibi ti won ti se ipade pelu awon elegbejegbe iyen gbongan OGD, se lose to n bo.L

No comments:

Post a Comment

Pages