Agbẹjọro Biyi Ọtẹgbẹyẹ, oludije Gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC, nipinlẹ Ogun, ti bawọn musulumi jakejado agbaye ṣajọyọ ayẹyẹ ọjọọbi Anọbi Mohammed,ti wọn ṣe iranti ẹ lonii.
Ninu atẹjade ti ikọ iroyin fun ọkunrin ọhun gbe jade lo ti gba wọn nimọran lati lo ayajọ ayẹyẹ ọhun lati fi ifẹ han sawọn musulumi ẹgbẹ wọn atawọn ẹlẹsin yooku.
Atẹjade ọhun tun lọ bayii ‘’ Inu mi dun pe Ọlọrun ka wa yẹ lati tun ri ayajọ ọjọọbi Anọbi wa, Mohammed, Mo ki gbogbo awọn musulumi ku oriire. Ayajọ ọjọọbi yii, mo fẹẹ ka fi maa ranti Anọbi wa, Mohammed, ati lati maa tẹle awọn ilana to fi fun wa ninu Kuran. Musulumi gbọdọ jẹ oluranlọwọ ẹgbẹ ẹ, bẹẹ o si gbọdọ maa fiwa ododo lati le jẹ ki alaafia jọba lawujọ wa’.
Oludije labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC, tun wa rọ gbogbo ọmọ ipinlẹ Ogun, lati ma ṣe gba jagidijagan to fa itajẹ silẹ laaye lakooko ti ipolongo ibo to n bọ fun ibo 2023.
O ni "Awa gẹgẹ bi ọmọ ipinlẹ Ogun, oloṣelu atawọn to n tẹle wọn, to fi mọ gbogbo araalu, a gbọdọ foju sọna, ki a si maa gbadura lati tako wahala ati ija ninu ibo to n bọ lọna’’.
No comments:
Post a Comment