Olota atawon oba Awori fowo si Asiwaju, Dapo, Adeola Yayi fun ibo to n bo - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 2 October 2022

Olota atawon oba Awori fowo si Asiwaju, Dapo, Adeola Yayi fun ibo to n bo



Olota tiluu Ota, Oba  Abdulkabir Adeyemi Obalanlege,atawon oba Awori ti won je ogoji nipinle Ogun, ti seleri pe awon setan lati satileyin fawon oludije ipo fegbe oselu APC, ninu ibo to n bo lodun to n bo.

Awon oba alaye naa seleri yii lakooko ti Seneto Solomon Adeola, topo mo si Yayi sabewo loo sodo won ni afin Olota.

Won so pe ki awon oludije yii bere lati ori Asiwaju Bola Ahmed Tinubu, to n dije fun ipo Aare, Gomina Dapo Abiodun, to fee dupo naa leekeji,Seneto Solomon Adeola, toun dije fun ipo asofin niluu Abuja fun ekun Ogun West atawon yooku fokanbale awon yoo satileyin fun won.

Awon Oba Awori naa tun fikun ninu oro won pelu awon ise rere tawon oludije yii ti se seyin, ti fihan pe o ye kawon fowo si fun won lati wole fun ibo yii.


Won wa seleri pe awon yoo bawon eeyan to wa labe won soro lati rii pe won ko so ibo won danu, won si fi gbe awon oludije yii wole.

 Ninu oro ti Olota lọ pe ipe fun isokan gbogbo omo Yewa ati Awori, ki won si le fimo sokan. O ni eyi lo le je ki won ni gomina lati odo won wa lojo iwaju.

O so pe "Mo fee ro Seneto Adeola, ko se awon ohun idagbasoke iru eyi to se nigba to soju won ni Lagos West. Mo sakiyesi pe irufe awon nnkan bee la n fe nile Awori.

Bee lo tun lo akoko naa lati bebe fun idasile igbimo lobaloba ti Awori ni Ogun West, o ni iru eyi yoo je ki idagbasoke tun dele de oko kaakiri ipinle naa.

Ko to to akoko yii ni Seneto Adeola ti so pe oun kan wa lati wa sabewo sodo awon oba naa ni, ati pe oun ko tii bere ipolongo . O so pe o digba ti egbe oselu APC lapapo ba fenu ko lawon yoo to bere.

O wa lo anfaani yii lati fi dupe lowo gbogbo awon oba naa fun atileyin ti won se fun ijoba Dapo Abiodun, fawon ise akanse to n se kaakiri. O ni ninu awon tawon jo dupo fun asofin yii, oun nikan loun si ni iriri pelu awon idagbasoke toun to mu ba Lagos West.




O ni lati akoko yii lọ titi de osu kejila, egberun kan awon to n gbe ni Ado Odo ni yoo gba idanilekoo ti won yoo si tun ro lagbara. Bee lo ni awon ona meji nile Awori loun yoo tun se..


O wa bebe fun atileyin Asiwaju Tinunu ati Dapo Gomina fun ibo to n bo lodun to n bo.
 
Lara awon to tele lo ni Igbakeji Gomina nipinle Ogun, Noimot Salako- Oyedele, Senato Kola Bajomo, Senato Akin Odunsi atawon mii in

No comments:

Post a Comment

Pages