Dokita ArabinrinJackie Adunni Kassim, oludije du ipo gomina labe egbe oselu NNPP nipinle Ogun, ti so pe oun ko se mo nitori iwa odale to ni won hu ninu egbe naa.
Obinrin yii soro naa lakooko toun atawon alatileyin e lati ijoba ibile Ogun, nipinle Ogun ba awon oniroyin soro, leyin ti won pari ipade egbe won kan ti won pe ni Iyadunni Movement.
O fesun kan alaga egbe naa Olaposi Oginni pe o n sise tako anfaani egbe naa koda leyin ti ajo eleto idibo INEC, ti koko daruko oun gege bi oludije gomina labe egbe oselu NNPP yii.
Adunni tun fi kun oro e pe irufe iwa ti alaga won n hu yii je eyi to lewu to si le mi akoba wa ninu ibo gbogbogboo to n bo naa fegbe oselu yii ati pe o tie ti je ko pin.
O fikun oro e pe"Mi o le maa wa ilosiwaju egbe kawon kan si maa ba a je.Erongba mi ni lati dije, ki n si jawe olubori, ki i se lati fikunlukun pelu egbe oselu mii in ti ibo ba sunmo etile".
O ni gbogbo awon lawon yoo so igbese mii in tawon yoo gbe, nitori ko si omoleyin oun kankan ti yoo jiya.
O ni gbogbo awon to n ba nnkan je ninu egbe naa ni won ki I se omo bibi ipinle Ogun, o was ro awon omo egbe e lati maa woye egbe oselu tuntun ti won yoo darapo.
Bakan naa ni gbogbo awon omo leyin ti won wa nibe lawon naa pinnu pe awon ko ba Oginni se papo mo.
No comments:
Post a Comment