Agbejoro Biyi Otegbeye, oludije gomina labe egbe oselu African Democratic Congress (ADC) nipinle Ogun, ti sapejuwe bi oruko e se jade ninu iwe ti ajo eleto idibo INEC, fi sita gege bi oludije ibo odun to n bo bi ipe lati sin, ti oun si ti setan
Okunrin naa soro yii lakooko ti oruko e jade lonii, o si so pe oun ti gbaradi bayii fun ibo to n bo lodun 2023 naa.
O so pe aseyori nla lo je, fawon akinkanju ise fun idi pataki oooto ti oun ni si egbe oselu toun ti jade iyen egbe oselu ADC kaakiri ipinle naa.
Otegbeye tun so pe" Mo mo pe latigba die seyin lawon eeyan ipinle Ogun ti n wa ayipada rere. Bee ni mo tun ri pe awon odo,awon ara oja, onise owo, osise feyinti atawon mii ii ni ijoba to wa lode yii n fiya je.Mo mu da yin loju pe gbogbo e ni yoo dopin ti mo ba gba akoso ninu osu karun-un odun 2023".
Oludije gomina ADC wa ro gbogbo omo egbe oselu ADC lati gbaradi fun ipenija nitori oun mo pe awon yoo jo se aseyori naa dele
No comments:
Post a Comment