Agbejoro Biyi Otegbeye, oludije gomina labe egbe oselu ADC nipinle Ogun, ti so pe ji jade toun jade yii ni owo Olorun ninu ati pe ise ti oba oke ti pari ni
Okunrin naa soro yii lakooko to sabewo lọ ki Olu Ilaro, Oba Kehinde Olugbenle ni afin e.
O so pe lati idibo meta to ti waye seyin iyen lati odun 2011 si 2019, ni won ti n lọ awon omo Yewa Awori lati maa fi tako ara won fun ipo gomina.
Otegbeye so pe " Ni odun 2011,Ogagun Olurin ati GNi, 2015, GNI ati Odunsi ati 2019, GNI ati Akinlade, ka ni isokan wa laarin awon mejeeji ti won dije ti won panupo fa oludije kale ni, Yewa ko ba ti ni gomina"
O wa ro awon eeyan ohun lati satileyin foun gege bi oludije kan soso lati jawe olubori ninu ibo to n bo lodun 2023.
O ni egbe oselu ADC ti setan lati ayipada rere ba ipinle Ogun. O waa ro won lati ma se je ki akoko yii tun fo won ru.
Ninu oro Kabiyesi, Oba Kehinde Olugbenle, o gbadura aseyori nla fun oludije to je omo bibi ilu won.
O ni oun nigbagbo pe Olorun to so oun di oba yoo je ki Otegbeye jawe olubori ninu ibo to n bo naa.
Bee lo gba won lamoran lati ma je ki itajesile waye lakooko ti ipolongo ba n lọ lowo
O so pe ki won ma se fi oruko Biyi Otegbeye da wahala sile ati pe ko seni to ta eje sile to ki i ri atubotan e.
Bee lọ ro oludije naa lati fi gbogbo e le Olorun lowo nitori oun lọ n gbe eeyan depo. O so pe ki okunrin naa ma se fi adura sile ko si nigbekele ninu Olorun.
No comments:
Post a Comment