Olorin emi nni Ajihinrere Abiola Fausat Fakoya, topo awon eeyan mo si Ayanfe Jesu ti so pe bi ki I ba se ipenija owo to n koju, ise iranse orin emi oun ko ba ti goke ju bayii lọ.
Arabian soro naa lakooko to n ba oniroyin wa soro, o ni ki i se pe oun sadeede bo sidi ise orin bi ko se pe oun gbo ipe.
O fikun oro e pe opo idojuko loun ti ba a pade nitori pe oun ko eti ikun lati tele Oro Olorun nipa ipe si orin kiko. Sugbon oun dupe lowo Olorun pe o fi aanu re gba oun.
Obinrin naa tun so pe aimoye imisi orin ni Olorun ti towo oun ko jade amo ti ko si oluranlowo ti yoo ba gbe e jade.
Bee ni Ayanfe Jesu to filu Sagamu se ibugbe tun salaye pe gbogbo ara loun sa lati ri I pe oun tiraka gbe awo orin jade, ti ko so bo si.
O ni bo tile je pe opo Ile ijosin ni won ti maa n pe oun lati was fi orin jere okan awon eeyan ti Olorun si n gba gbogbo ogo.
O was ke si awon eleyinju aanu lati ran ise iranse e lowo, ki ara ma ba a pare mo on nikun.
No comments:
Post a Comment