Mo darapọ mọ PDP lati gba ipinlẹ Ogun silẹ- Onarebu Adekunle Akínlàdé - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 4 August 2022

Mo darapọ mọ PDP lati gba ipinlẹ Ogun silẹ- Onarebu Adekunle Akínlàdé

 

Ọnarebu Adekunle Akinlade, tẹgbẹ oṣelu PDP, ipinlẹ Ogun, fa kalẹ gẹgẹ bi igbakeji fun oludije gomina iyẹn Ladi Adebutu, fun ibo gbogbogboo to n bọ lọdun 2023, ti tan imọlẹ lori bo ṣe darapọ mọ PDP yii.

 

Ninu ọrọ tpo sọ nigba to n ba  ‘’Coalition of Media Giants and socials stakeholders on Ogun Project, eyi ti Ọnarebu  Kẹhinde Ṣoaga (dgn), ṣagbekalẹ ẹ lo ti sọ pe lati ọdun 2019, lawọn eeyan ko ti jẹ mudunmudun iṣejọba, ti wọn si ti ja awọn araalu kulẹ.

 

Ọkunrin oloṣelu ọhun tun fi kun ọrọ ẹ pe ki awọn eeyan lọ kaakiri igboro, ki wọn lọọ wo bijọba APC, to wa lode naa ṣe kuna patapata, ti wọn si n fara ni awọn araalu.

 

Akinlade tun sọ pe ‘’ Mo fẹẹ ki ẹ mọ pe oun ta a n fẹ lakooko yii nipinlẹ Ogun ni bi ilọsiwaju yoo ṣe ba  gbogbo awọn olugbe to n gbe nibẹ ati bi igbe aye irọrun yoo ṣe jẹ pataki, idi niyii ti mo fi darpọ mọ ikọ Ladi Adebutu, lati le gba wa lọwọ awọn ti ko bikita fawọn araalu, inu awọn eeyan wa ko dun rara, wọn si n fẹẹ ayipada ẹgbẹ oṣelu tuntun’’

 

Lori idi to fi tete kuro ninu ẹgbẹ APC, to wa tẹlẹ, Ọnarebu Akinlade, sọ pe ´´ Lakooko ta a wa yii, nnkan kan tawọn araalu n fẹ ni ẹni ti yoo mu irọrun ba wọn, ti yoo si gba wọn lọwọ igbekun ti wọn wa, ibo to n bọ lọdun 2023, ni ọna kan gboogi lati bọ lọwọ wọn, nipa ibo’’

Bakan naa lo tun sọrọ lori ibeere kan ti wọn beere lọwọ ẹ pe ṣe Amosun, to jẹ ọga ẹ, fọwọ si bo ṣe bọ sinu ẹgbẹ tuntun ọhun, Ọkunrin naa sọ pe ọga oun nikan lo le dahun ẹ, ṣugbọn oun mọ pe Gomina tẹlẹ nipinlẹ naa n fẹ nnkan rere fawọn eeyan ipinlẹ Ogun, ti yoo si fọwọ si pẹlu.

 

 O waa sọ pe ninu oṣu yii ni lawọn ilana ti yoo mu aye rọrun ti ẹgbẹ ọhun ni fawọn eeyan yoo jade.

 


No comments:

Post a Comment

Pages