Bi eto idibo gbogbogboo fọdun 2023, ṣe n wọle bọ ti ọpọ awọn oludije si n jade fun ipo kan si omii, ni bayii, awọn eeyan agbegbe Ewekoro/ Ifọ ti sọ pe lẹyin Ọmọọba Jide Fadairo, ko tun si ẹlomii tawọn yoo ṣatilẹyin fun lati gba tikẹẹti aṣoju-ṣofin, ti ọkunrin naa jade fun, nitori oun ni Ọlọrun ran si awọn, tawọn si mọ pe o kaju ẹ lati le ṣe e.
Okunrin kan to ba oniroyin wa sọrọ, Ọladele Lawal, to jẹ ọkan lara awọn to n gbe lagbegbe naa sọ pe gbogbo ẹnu loun fi le sọ pe Ọmọọba Fadairo, kun oju oṣuwọn lati ṣoju wọn, tawọn ba fun un laaye.
O sọ pe ninu iriri ki eeyan mọ nnkan ti araalu n fẹ, oludije yii ni, o si mọ nipa ẹ daadaa, to si da oun loju pe ilọsiwaju ati idagbasoke yoo tubọ ba awọn eeyan to fẹẹ soju fun ju ti tẹlẹ lọ.
Arabinrin Funmi Ajao, ni tiẹ sọ pe ko si awawi kankan, ireti tawọn ninu Jide Fadairo, to ba wọle ki i ṣe kekere, nitori Ọlọrun mọ ọn mọ fẹẹ fi jinki awọn ni.
Obinrin yii sọ pe’’ Ẹ jẹ ki n sọ kin ni kan fun yin iru eeyan bi ti Jide Fadairo sọwọn laarin awọn oloṣelu, oore ọfẹ nla ti Ọlọrun fẹẹ fun wa ni, ko si waa yẹ ki a wa fọwọ wa sọ nu, a wu mi ki a fun laaye lati wọle fun aṣoju-ṣofin fun agbegbe wa, ko le ba ran awa naa lọwọ’’
Bakan naa ni Abileko Funmi Ajao sapejuwe Omọọba Babajide Fadairo gege bi Eni ti Olorun Didi fun agbegbe Ewekoro ati Ifo konsituensi, o wa ro awon eeyan lati gbaruku tii ko le wa lo awon Iriri to ni nileyi ati oke Okun lati Fi mu Idagbasoke ba Ijoba Ibile Ifo ati Ewekoro konsituensi .
Gbogbo isarasihuwa Omọọba Jide lo ti Fi han pe o ti gbaradi fun lpo naa.
Ibrahim Fasasi, toun jẹ ọkan lara oṣisẹ ijọba ni agbegbe Ifọ, sọ pe odu ni Fadairo ki i ṣaimọ foloko lagbo oṣelu, bẹẹ lo si ti ṣatilẹyin fun ijọba Gomina Ipinlẹ Ogun,Ọmọọba Dapọ Abiọdun ninugbogbo igbese rẹ.
O ni o wa lara awọn ti wọn gba kiỌmọọba Dapọ Abiọdun tun ṣeẹlẹẹkeji, ko le pari awọn iṣẹ nla to dawọle .
Omọọba Jide Fadairo, ni wọn bi si agboole idile oye LIoyd AfọlabiFadairo, ti Amọroro, laduugbo, Ele,ni Owu, niluu Abẹokuta, lpinlẹOgun, lọdun 1967.
Oloogbe Afọlabi Fadairo, to jẹ baba ẹ ni alaga akọkọ nijọba ibilẹEwekoro, lọdun 1981 si 1983,lasiko ijọba Bisi Ọnabanjọ.
Ọdun 1990, ni Jide gba gba oye ninu ẹkọ, ni oke- okun.
O ṣe idanwo lọdun 1991, ti wọn si fun un niwee aṣẹ lati ma ṣiṣẹ.
Lẹyin naa ni oke –okun, wọn tunfun un laṣẹ lati ma ṣiṣẹ, ti wọn tun fun lawọn nnkan ti yoo fi maa ṣe.
Ọdun 2005, lo pada si Naijiria to sida iṣẹ silẹ fun ara ẹ. Lọdun 2012,lo bẹrẹ iṣẹ pẹlu Ileeṣẹ ti Ọba Ẹnitan Ogunnusi, da silẹ niluu Eko.
Nigba ti yoo fi ọdun 2016, o di adari Ileeṣẹ Oduduwa Foundation, ti Ooni gbe kalẹ.
Ọmọọba Babajide Fadairo tun jẹagbaninimọran fun Ọba ẸnitanOgunnusi.
No comments:
Post a Comment