Ilu Abẹokuta mi titi lọjọ ti Biyi Ọtẹgbẹyẹ kede lati dije fun ipo gomina nipinlẹ Ogun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday 24 May 2022

Ilu Abẹokuta mi titi lọjọ ti Biyi Ọtẹgbẹyẹ kede lati dije fun ipo gomina nipinlẹ Ogun


Nigba ti wọn kọkọ gbọ pe Amofin nni Biyi Ọtẹgbẹyẹ fẹẹ jade dupo ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, awọn eeyan ko tete gbagbọ, ero ọkan wọn ni pe boya ipo mii in lo jade fun.

Ṣugbọn nigba ti wọn tun ri awọn aroko ti ọkunrin naa lati fi bawọn eeyan sọrọ, nibẹ lawọn kan ti n fura pe ṣe loootọ ni Ọtẹgbẹyẹ fẹẹ jade ati pe ipo wo gan-an lo fẹẹ lọ fun.

Ohun to tun waa jẹ ki ọrọ naa tun fi daru mọ wọn loju ni pe gbogbo bawọn oludije mii in ṣe n gba fọọmu, ti wọn n ṣe afihan pe awọn ti gba fọọmu lati dije, Biyi Ọtẹgbẹyẹ, ko ṣe bẹẹ.

Nitori ẹ lawọn kan ṣe n beeere lọjọ Aje, Mọnde, to kọja yii nigba ti wọn gbọ pe ọkunrin yii fẹẹ ko ara ẹ jade gẹgẹ bi ọmọ tuntun lati kede pe oun fẹẹ dupo gomina ọhun.

Ohun to jẹ ko tubọ ya awọn eeyan lẹnu pe eto ti wọn ṣe lọjọ laaarin wakati mejila, ti wọn fi ṣeto ẹ, amọ beeyan ba de gbọngan OK Events Centre, to wa ninu Ibara Housing, niluu Abẹokuta, yoo ro pe boya wọn ti polongo ẹ tẹlẹ ni, nitori bawọn eeyan ṣe tu yẹyẹ jade lọjọ naa

To si jẹ pe binu gbnọgan ọhun ṣe kun fọnfọn bẹẹ naa nita naa o gbero, ariwo ti wọn si n pa ni pe ‘’Biyi ni Gomina, Ọtẹgbẹyẹ ni Gomina’’  Oloye Derin Adebiyi, lo ṣaaju awọn oloye ẹgbẹ ti ikọ Sẹnetọ Ibikunle Amosun lọọ sibi eto ọhun. Ohun to tun wa jẹ iwuri lọjọ naa ni bi Ọnarebu Adekunle Akinlade, toun naa dije fun ipo gomina ṣe yọju lọjọ naa.

 

Nigba to n ba awọn eeyan sọrọ nibi ayẹyẹ naa. Biyi Ọtẹgbẹyẹ mu da awọn eeyan loju pe bi ogo ti n jẹ ti Ọlọrun, ti wọn ba le dibo yan oun gẹgẹ bi Gomina nipinlẹ Ogun, oun yoo rii pe ipọnju ati oṣi di afisẹyin, bẹẹ loun yoo si ri pe gbogbo ipenija lori eto aabo wa ojutu si.

 

Ọtẹgbẹyẹ to jẹ oludasilẹ ileeṣẹ idojutofo ‘’Providence Trust Insurance Company’’ wa lo akoko naa lati rọ awọn aṣoju lati dibo foun ninu ibo abẹle to n bọ l’Ọjọbọ, ọsẹ yii, oun si ti ṣetan lati gba ipinlẹ Ogun lọwọ ijakulẹ eto ọrọ aje, ki ayipada rere si de ba gbogbo mutumuwa.

 

Ninu ọrọ tiẹ, Sẹnetọ Iyabọ Aniṣulowo, rọ awọn aṣoju lati jẹ ki tikẹẹti ẹgbẹ oṣelu APC, tẹ Biyi, ẹni to ṣapejuwe gẹgẹ bi agbejọro, to si tun jẹ adojutofo, o ni awọn iriri ti ọkunrin naa ni ti to fun lati dari ipinlẹ Ogun.

 


No comments:

Post a Comment

Pages