Bi awon omo ile igbimo
asofin agba se bere isinmi olose meji bayii, Gomina Dapo Abiodun, tipinle Ogun
ti ki awon eeyan naa ku oriire pelu amoran pe ki won lo isinmi ti won n lo naa
lati fi sabewo sawon ti soju fun lati mo awon eto ti won n fe lawon agbegbe won
lati fi sagbega fun eto isejoba tuntun yii..
Ninu atejade ti akowe
iroyin gomina, Ogbeni Kunle Somorin, fi sita lo ti fi idunnu e han lori aseyori
ti won se lati yan awon asaaju won fun ile igbimo asofin eleekesan ni asofin
agba ati asoju-sofin.
O ni ibo awon asaaju
asofin to waye nirowo rose je eyi to dara ju to mu idagbasoke ba ijoba
tiwa-n-tiwa ba orileede wa. O ibo to gbe Seneto Ahmad Lawan ati Femi
Gbajabiamila gege bi olori ile igbimo asofin ati asoju sofin tun je ki isokan
tun joba pelu.
Gomina Abiodun tun
salaye siwaju pe ibo to waye laarin awon naa ko ya oun lenu, eyi fihan pe won
fun Mohammed Buhari latileyin to lagbara lati le seto ijoba tiwa-n-tiwa lona ti
yoo mu irorun ba araalu.
O wa so pe bi gbogbo
wa se n foju sona lati je ki isokan tun joba lati le je ki orileede yii tun
dagbasoke, o ro awon omo ile igbimo asofin pe ise won ni lati koju mo sise awon
ofin ti yoo tubo mu isokan ba wa fun ti isejoba tuntun.
O wa tun ro won lati
fara won ji ki erongba ipele miran an ti Buhari rawo le nini ijoba eleekeji e
yii ko le kese jari, ko si le ni itumo rere ninu igbe aye awon omo orileede
yii.
Bee lo tun gba lamora
ki won ma se fi awon ofin ti won ba n se fale rara.
No comments:
Post a Comment