Seneto Solomon Adeola topo mo si
Yayi to je oludije fun ipo gomina labe egbe oselu APC nipinle Ogun ti gboriyin fun
Oloye Olusegun Obasanjo, Gomina Ibikunle Amosun ati Oloye Olusegun Osoba
fatileyin won fun awon Yewa lati di gomina fodun 2019 gege eyi to dara ju.
A o ranti pe lati bi
odun mejilelogoji seyin, ko ti si omo Yewa Awori kankan to ti depo gomina nigba
tawon ekun meji yooku ti won jo n je ipinle Ogun ti je gomina,sugbon ti won ko
fawon ekun Yewa yii lanfaani lati de be.
Lakoko to n ba awon
omo egbe atawon oba alaye peluu awon elegbejegbe to fi mo awpn oloja soro niluu
Ayetoro,Yewa North, Seneto Yayi so pe kii se nnkan to dara to si bojumu pe ko
maa ti si omo Yewa kankan ti yoo dori ipo gomina niwongba tawon ekun yooku ti n
je eyi si ni ko je kawon idagbasoke to ye ko ti de ba Ogun West ti de,ifaseyin
lo ni o mu wa peluu.
Seneto Adeola tun so
pe" Mo fee dupe lowo Baba wa, Oloye Olusegun Obasanjo,Gomina wa, Ibikunle
Amosun fun bi won se so Nita gbangba pe awon setan lati satileyin fun In Ogun
West lati di gomina fodun 2019 peluu tokantokan won.Apeere rere ti ko ni kuro
ninu itan fun idagbasoke ipinle ni won fi le le yii."
Bakan naa lo gba won niyanju lati ma se se ojusaju lati fa
oludije tabi fagbara fa oludije kale le awon eeyan Lori, ki won je kawon eeyan
mu oludije to ba wu won, nitori bi Iru nnkan bee ba sele, aye lati je
kawon ekun yooku tun wole si won lara ni,gege bi eyi to ti maa n waye tele. O
ni bi ogiri ko ba lanu alangba ko le wobe.
O so pe o wa ninu
itan pe nigba ti Ogun Central ati Ogun East fa gomina kale,won mu won nitori
won gbajumo to si tun je atewogba araalu, kii se pe won gbe le awon eeyan lori,
o ni tawon Ogun west naa ba le se eleyii yoo je ki idagbasoke some bawon.

Ko to to akoko naa ni Seneto ti se abewo loo sodo Alaye
tiluu Ayetoro atawon ijoye e nibi to ti seleri lati je ki transifoma iyen ero
amunawa to ti pese fun won bere ise ni kiakia.
Lara awon to wa peluu Seneto lojo naa ni
Onarebu Kunle Adesina , olori ile igbimo asodin tele. Tunji Egbetokun,
Alaaji Aliu Ajibode, Alaaji Fatai Ajibode, Aare Tunde Alabi,Tunji
Osibote.
No comments:
Post a Comment