Gbajumo olorin Islam nni, Alhaja
Rodiya Sanni- Adeboye, eni tawon eeyan tun mo si Hello Olohun ti gbe
rekoodu tuntun mi in jade bayii to pe akole e ni Allahu ni.
Rekoodu tuntun yii ni yoo je
elekeerin ti Alhaja Rodiya yoo gbe jade. Saaju asiko yii lo ti gbe awon
wonyi;.Hello Olorun, Islamic News ati I love Mohammed jade.
Ninu oro e naa lo ti so pe,
"Akori orin orisi meta la ko sinu e. I don't know why, Alhamdulilaa ati Aso
Oge. Ohun to je wa logun ni bi a o se lo orin wa lati safihan esin alaafia ati
esin asinla ti Islam n se."
Lara awon gbajumo olorin ti Rodiya
ti jo se rekoodu papo daadaa lopo igba ni Alhaji Wasiu Alabi Pasuma, Mariam
Akiiki, Alhaji Qamardeen Odunlami Ayeloyun.
Ninu oro e lo ti salaye bayii pe,
"Ohun to mu orin mi yato pupo ni pe, oro inu Kuraani ati awon iwa daadaa
ti Anobi fi ko wa lemi maa n lo fi se waasi ninu orin mi, eyi naa lo so orin mi
di gbajugbaja loke okun, ti mo si tun ni awon ololufee daadaa ni Nigeria bakan
naa."
Alhaja Hello Olohun ti ro awon
olorin Musulumi lati maa fi ipaya Olorun korin, ki won si je awokose rere
laarin awon Musulumi.
Okan lara awon olorin esin Islam to
n se daadaa lasiko yii ni Alhaja Rodiya Sanni- Adeboye to fi ilu Dublin
lorile-ede Ireland sebugbe. Ise Noosi gan an lo gbe e de ilu oyinbo, bee lo tun
je olorin nla tawon eeyan mo kaakiri ile Europe ati Amerika.
No comments:
Post a Comment