Oludije Gomina fẹgbẹ oṣelu YPP nipinlẹ Ogun, Cyprus Oluwafẹmi Johnson Akinfẹnwa, ti mu da gbogbo ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ nipinlẹ naa loju pe ayipada rere yoo tunbọ si deba wọn bu wọn ba le fibo wọn gbe oun wọlẹ lọdun to n bọ.
O sọrọ yii lakooko to n ṣe ipade ipinnlẹ ẹ to ba depo gomina fẹgbẹ awọn oṣiṣẹ, eyi to waye ni ọfiisi wọn Lọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.
O sọ di mimọ pe bijọba kan ba fẹẹ ṣe aṣeyọri kọ gbọdọ kọyan awọn oṣiṣẹ kere nitori awọn gan an ni adun to wa ninu ọbẹ ijọba.
Ọkunrin naa ṣalaye siwaju pe iṣejọba ki i ṣe lati lọọ jokoo si ọfiisi ko maa paṣẹ bi ko ṣe pe lati wa ọna ti igbe aye awọn to n ṣejpba le lori yoo ṣe ladun, ko si mu awọn ohun idagbasoke rere ba wọn.
O fikun ọrọ ẹ pe ijọba to ba da awọn oṣiṣẹ ijọba nu, ti ko ni akasi wọn, o lo dabi ẹni naa ṣe afọwọfs bi oun gan an ko ni ṣe tijọba naa ṣe.
Akinfẹnwa tẹsiwaju pe ọpọ igbesẹ loun yoo gbe toun ba dori ipo lati rii pe ajọṣepọ to danmọran wa laarin ijọba ati ẹgbẹ oṣiṣẹ.
Bẹẹ lo ṣeleri pe oun yoo fiwe nnkan ti mo maa ṣe re e ti mo ba depo iyẹn manifesto ranṣẹ sawọn ẹgbẹ oṣiṣẹ.
Ninu ọrọ Arabinrin Fọlaṣade Ọmọyẹni, to ṣoju alaga ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ, Hammed Benco Ademọla, lọjọ naa lo ti ṣalaye pe idi tawọn fi gbe eto biba awọn oludije sọrọ nii lati jọ fikunlukun nipa nnkan ti wọn ni fẹgbẹ oṣiṣẹ ti wọn ba depo.
Lara awọn to tẹlẹ Oludije Gomina YPP lọ sibi ipade ọhun ni alaga wọn, Ọgbẹni Adeyẹmi Oluwaṣeyifunmi.
No comments:
Post a Comment