Nibi ayẹyẹ iṣipo pada ọhun eyi to waye ni oluuleṣẹ wọn to wa ni Idiroko, ni wọn ti ṣapejuwe Afẹni, ti wọn ti gbe oun naa lọ si Eko, bi akọni tawọn akọsilẹ ẹ lẹnu igba to fi wa ni Ogun ko le parẹ.
Wọn ni akikanju to farajin fun iṣẹ to yan an laayo, to si ni aṣeyọri rere lati Januari ọdun 2026 titi di oṣu kẹjọ nipa pipa owo wọle si asunwọn ijọba, eyi tawọn owo naa le ni biliọnu mẹrin naira.
Ninu ọrọ ẹ lo ti kọkọ dupẹ lọwọ awọn ọmọ abẹ fun ifọwọsowọpọ ti wọn ni pẹlu lakooko to fi jẹ ọga wọn.
O ni ọpọ aṣeyọri toun ṣe yii nipaṣe pe wọn jọ wa ni irẹpọ ati iṣọkan ni gẹgẹ bi owe Yoruba to sọ pe igi kan ko le da igbo ṣe.
Bakan naa lo tun fun ẹmi imoore ẹ han si awọn eleto abo yooku nipinlẹ Ogun fawọn ajọṣepọ to danmọran laarin wọn.
Bẹẹ lo fi awọn aṣeyọri ẹ sọri ọga agba pata lorileede yii fun ẹṣọ aṣọbode, Adewale Adeniyi, fun ẹmi igbagbọ ati ifọkantan to ni si oun lati le wa dari ipinlẹ Ogun.
O wa ṣeleri pe oun ko nii ja nitanmọ nibi gbogbo ti wọn ba gbe oun lọ lati lọọ sin wọn gẹgẹ bi iṣẹ toun yan an laayo.
Nigba to n tẹwọ gbaṣẹ lọwọ Afẹni, Ibrahim dupẹ lọwọ ọga agba tẹlẹ naa bẹẹ lo gboriyin fun fawọn akọsilẹ aṣeyọri to ṣe e.
O wa ṣeleri pe oun yoo tẹsiwaju nibi apẹẹrẹ rere ti Afẹni fi ṣilẹ, oun si ti ṣetan lati faraji ki iwa fayawọ le dinku patapata nipinlẹ Ogun.
No comments:
Post a Comment