Bẹẹ lo tun kesi wọn pẹlu lati dibo fun Gomina Dapọ Abiọdun, lati wọle sipo aṣofin agba to n dije fun ni ẹkun Ogun East.
O sọrọ yii lakooko to n ba awọn ọmọ ẹgbẹ ati alatilẹyin ẹgbẹ APC fọrọ jomi toro ọrọ niluu Ijẹbu Igbo lonii.
O sọ pe oun wa si Ijẹbu Igbo ki i nipa aṣeyọri fun ibo aarẹ bi ko ṣe pe oun wa bẹ wọn ki wọn jade lọpọ yanturu lati wa dibo fun aarẹ, ki ibo naa le pọ jaburata.
Ṣẹgun Ṣowunmi tun tẹsiwaju ninu ọrọ ẹ pe ko si idi pataki ti ibo ipinlẹ Ogun fun ipo aarẹ ko ba pọ lati fi ṣoroogun awọn ipinlẹ Hausa bii Kano, Kaduna tabi Kastina.
O ni ko si nnkan to buru bi Aarẹ Tinubu ati Gomina Abiọdun ba ri ibo to pọ, ti ko lonka ninu ibo ọdun 2027.
Bakan naa lo tun kesi gbogbo awọn ọmọ orileede yii lati ma tẹti si isọkusọ tawọn kan sọ nipa ilera Tinubu. O sọ pe ko si nnkan to ṣe e, ṣe lara ẹ le koko.
Ṣowunmi ni bi Aarẹ ko ṣe yọju sibi ipade ajọ agbaye iyẹn UN,ko ni nnkan ṣe pẹlu ilera ẹ niwọngba ti igbakeji ẹ, Alaaji Shettima ti wa nibẹ.
O wa kesi awọn alatako nidii oṣelu lati ma ṣe maa fawọn nnkan to le mu idagbasoke ati ọrọ aje bọnu oṣelu.
O wa lo akoko ọhun lati kesi gbogbo ọmọ Ogun East lati ma ṣe je ki ibo aṣofin agba bọ mọ Gomina Dapọ Abiọdun lọwọ.
O lawọn nnkan manigbagbe ni Dapọ ti ṣe si agbegbe ọhun gẹgẹ bi Gomina toun si nireti pe yoo ṣe ju bẹẹ lọ to ba wọle fun ipo sẹnetọ.
No comments:
Post a Comment