Ẹyin ti Ogun Central, ẹ lọọ gba kaadi idibo yin lati fi le APC lọdun 2027-Abiọdun-Oni - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday, 11 October 2026

Ẹyin ti Ogun Central, ẹ lọọ gba kaadi idibo yin lati fi le APC lọdun 2027-Abiọdun-Oni


-Bakan naa lo rọ wọn lati ma ṣe ta kaadi idibo wọn foloṣelu kankan


Ọnarebu Samuel Oluwafẹmi Abiọdun-Oni, oludije ipo sẹnetọ fun ẹkun aarin gbungbun Ogun iyẹn Ogun Central, labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC, ti rọ awọn eeyan eeyen ipinlẹ Ogun paapaa julọ awọn to fẹẹ lọ ṣoju fun lati lọ gba kaadi idibo wọn, eyi ti ajọ eleto idibo INEC n pin.

Ninu atẹjade kan to fi sita lo ti rọ awọn eeyan ti wọn ko ti gba kaadi idibo ọhun tẹlẹ ṣugbọn ti wọn ti forukọ silẹ ki wọn ya tete lọ gba a bayi ki gbede ke ọjọ ti wọn fun wọn to pari.

Oludije naa sọ pe kaadi idibo wọn yii ni ẹtọ ti wọn ni lati fi le ẹgbẹ oṣelu APC kuro ninu ibo ti yoo waye lọdun to n bọ.

O ṣalaye pe gẹgẹ bi gbogbo awọn araalu ṣe mọ ti wọn si ti n gbaradi fun ibo to n bọ ninu eyi toun ti dije gẹgẹ bi aṣofin fun Ogun Central, kaadi idibo yii ni nnkan ṣoṣo ti wọn fi le dibo foun gẹgẹ bi aṣoju wọn

Bakan naa lo rọ wọn lati ma ṣe ta kaadi idibo wọn foloṣelu kankan labẹ bo ti wu ko ri.

Abiọdun-Oni tun ṣalaye siwaju pe bigba teeyan ba n ta ọjọ ọla eeyan loun ri ki awọn araalu ma ta kaadi idibo wọn fawọn oloṣelu, nitori ko si oore kankan to le ṣe fun wọn.

O ni gbogbo wa,lati foju winna awọn inira tijọba to wa lode lorileede yii ti foju wa ri paapaa ni Ogun Central, ẹni to yẹ ko mu ohun rere wa, to kan lọ n fi akoko ṣofo.

Awọn ẹtọ to fi mọ iṣẹ akanṣe to yẹ ko fi rọ wa lọrun, ẹni ẹlẹni lo tun gbaṣe wọn ṣe ti ko yẹ ko ri bẹ, idi  niyi to fi ke si awọn eeyan agbegbe ẹ lati ri pe wọn jade dibo pẹlu kaadi idibo wọn iyẹn PVC.

No comments:

Post a Comment

Pages