Ninu atẹjade jade to fi sita lo ti ṣalaye pe titi di akoko yii egbo ọkan ti iku Oloye MKO Abiọla da silẹ latigba ti wọn ti padanu ẹ ko ti jinna.
O ni iku ẹ atawọn nnkan to so mọ ọn fun ijangbara ijọba tiwantiwa ti June 12 ṣi maa n ko ẹdun ọkan ba oun pẹlu. Nitori idi eyi ko si nnkan toun fi le ṣe akawe irubọ oun lorileede yii nipa irinajo ijọba dẹmokireesi latigba naa di akoko yii.
O sọ pe, "Mi o ni fẹẹ ki ẹnikẹni ṣi mi gbọ rara, nitori ẹ ni mo ṣe ma tun ọrọ mi sọ, ohun ti mo sọ ni pe ko si ninu awọn oludije atawọn ti wọn lawọn yoo fi esi da wahala silẹ pe ki wọn sọra ki wọn ma baa ko wa sinu laasigbo.
O loun tọka si iṣẹlẹ ọdun 1992 lati ṣalaye bi ipo oṣelu yoo ṣe ri eyi ti ko ṣe e ṣakoṣo mọ bi a ko ba sọra.
Ṣowunmi ni, "Awọn to mọ oye ọrọ yii wọn o mọ nnkan ti mo sọ, mo si duro lori ọrọ ti mo sọ, nitori ikilọ ni mo fi ṣe nipa awọn nnkan to le ṣẹlẹ, mi o si ni jẹ kawọn ti ko fẹẹ ilọsiwaju orileede yi imọran mi pada."
O waa fi ọrọ Yoruba kan fi ẹsẹ ọrọ ẹ mulẹ, eyi to wi pe,“Tí mo bá gbà ẹ ní àmọ̀ràn mi, kò fẹ́ kó gbọ́; nítorí tí kò bá gbọ́, báwo ni màá ṣe jẹ́ ìfààrà rẹ̀, tí wá fi gbà mí ní ọlọ́gbọ́n?”
Ọdọfin Kemta ni iṣẹ oun ki oun gba awọn ọmọ orileede lamọran ni eyi ti yoo mu anfaani, lati wa gba gbọ wa lọwọ wọn.
O loun tun fẹẹ kawọn eeyan mọ pe ojulowo ọmọ orileede yii loun bẹẹ loun ko si nigbagbọ ninu ki wọn ma gbe ẹya kan gori ọkan.
Lori MKO Abiọla, o gbadura fun un pe ẹmí ẹ to fi le lẹ lori ijọba tiwantiwa ko ni ja si asan.
O wa sọ nigbẹyin pe," Ki wọn ma jẹ kawọn kan ma ro pe boya oun ko mọ itan tabi ki wọn ro pe mi o mọ nnkan ti mo n sọ, awọn to mọ nipa iku MKO Abiọla, ko le fọrọ mi da, tabi ki wọn sọ pe irọ ni mo n pa"
O ni oun ni ifarajin si orileede yii,pẹlu idurosinsin ninu ijọba tiwantiwa bẹẹ ni ọwọ toun ni fun bi MKO ṣe fẹmi ẹ rubọ ko kuro nibẹ,ati pe igbagbọ oun pe ki orileede bọ sinu ogo, ati ayipada rere ko yẹsẹ pẹlu
No comments:
Post a Comment