O sọrọ yii lakooko to n fikunlukun pẹlu ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ipinlẹ naa lori awọn nnkan to ni fun wọn to ba fi le wọle gẹgẹ bi ọkunrin naa.
Gẹgẹ bo ṣe wi gbogbo ọna loun yoo wa lati ri pe opin de ba awọn idojukọ tawọn araalu koju. O sọ pe ki i ṣe pe oun wa lati wa sọ asọdun bi awọn oloṣelu kan ti wọn yoo ṣeleri awọn nnkan ti wọn ko le ṣe.
Adenuga sọ pe bigba ti wọn ba gbe nnkan toun mọ jẹ de ati iṣẹ toun ṣe gẹgẹ bi onimọ ẹrọ loun ri bi oun yoo ṣe tete wa ọna abayọ sawọn iṣoro to n dojukọ wọn nipa ina.
Gẹgẹ bo ṣe wi, o ni ipa pataki ni ina ati omi n ko ninu igbe aye ọmọniyan, nitori e lo ṣe jẹ pe ẹni to ba fẹẹ ṣe gomina ko nii jẹ kawọn araalu ẹ maa koju iṣoro ẹ.
Oludije ọhun tun ṣalaye siwaju pe erongba oun lati mu idagbasoke wa jẹ ti agbaye eyi ti yoo bẹrẹ nipinlẹ Ogun, ti yoo si tun tan ka awọn ipinlẹ mi kaakiri orileede yii.
Bẹẹ lo tun mẹnuba awọn ipinnu to ni lọkan lati jẹ ki atunṣe ba ileeṣẹ redio ati tẹlifisan to jẹ tipinlẹ ọhun ni ọna ti yoo bs fi awọn akẹgbẹ ẹ dọgba.
Bẹẹ lo tun sọ pe awọn ọlọja lọkunrin ati lobinrin ni eto wa fun ninu ijọba wọn ti wọn ba fi le dibo yan oun wọle.
O wa bẹbẹ fun atilẹyin fẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lati dibo fun ẹgbẹ oṣelu BOOT, ninu ibo to n bọ pẹlu ileri pe oun ko nii jawọn ni tan mọ ọn.
No comments:
Post a Comment