Posita mi ti ẹ n fa ya, ẹ tun fi polongo mi faraalu ni-Sẹnetọ Iyabọ Ọbasanjọ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday, 4 September 2026

Posita mi ti ẹ n fa ya, ẹ tun fi polongo mi faraalu ni-Sẹnetọ Iyabọ Ọbasanjọ

Ṣe ni ọna oṣelu ipinlẹ Ogun tun ti gbọna mi yọ lakooko yii  nitori bawọn kan ti ẹgbẹ oṣelu PDP fura si pe o jẹ APC, ṣẹ bẹrẹ si nii fa awọn iwe ipolongo to jẹ ti Iyabọ Ọbasanjọ ya.

Sẹnetọ Iyabọ Ọbasanjọ, oludije fun ipo aṣofin agba labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, fun ẹkun aarin gbugbun ẹkun Ogun Central ni a gbọ pe awọn tọọgi oloṣelu kan ti n fa posita, patako ipolongo ibo ẹ ya kaakiri, ni eyi tawọn araalu ni ko bojumu.

Gẹgẹ bi awọn ọmọlẹyin Iyabọ Ọbasanjọ ṣe wi, wọn lo ti fẹẹ di gbogbo igba bayii tawọn tọọgi ti wọn wa lẹyin APC yoo maa huwa yii to si jẹ pe awọn ibi to ṣe pataki kaakiri ti wọn ba ti ri ohun elo ipolongo oludije wọn ni wọn maa n bajẹ.

Wọn ni iru nnkan bẹẹ ti waye nidii oṣelu ri nipinlẹ Ogun, to jẹ pe bi wọn ba ti ri posita awọn alatako oṣelu, wọn kii bikita lati ba a jẹ, iru ẹ lo tun fẹẹ bẹrẹ yii.

Ohun taa si gbọ pe o n fa ko le ju bi Sẹnetọ Iyabọ Ọbasanjọ ṣe n lọọ kaakiri igberiko lati bawọn eeyan sọrọ nipa erongba ẹ fun ibo to n bọ lọdun 2027.

Ṣugbọn ni bayii, alakoso agba fun eto ipolongo fun Iyabọ Ọbasanjọ, Donaldson Biodun Ajayi, ti sọ pe awọn ko ri tawọn to n ba ohun elo ipolongo oludije wọn jẹ ro.

Wọn eyi to ṣe pataki lọkan wọn ni bi oludije wọn,Iyabọ Ọbasanjọ yoo ṣe jawe olubori nibi ibo to n bọ lọna.

O ṣalaye pe fifa posita tabi ba patako aworan oludije wọn jẹ ko sọ pe ki awọn araalu maa dibo wọn fun ẹni ti ọkan wọn fẹ, ti yoo mu idagbasoke bawọn.

Ajayi ṣalaye siwaju pe awọn ti wọn jẹ ki wọn maa lo awọn yii ti gbagbe ni pe ṣe lawọn ti wọn ma ran wọn niṣẹ fidijanlẹ ninu ibo nigbẹyin.

No comments:

Post a Comment

Pages