Ile ẹjọ to ga ju ko wahala nla ba Iyabọ Ọbasanjọ, o ṣee ṣe ko ma dije fun ipo sẹnetọ aarin gbungbun. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday, 25 September 2026

Ile ẹjọ to ga ju ko wahala nla ba Iyabọ Ọbasanjọ, o ṣee ṣe ko ma dije fun ipo sẹnetọ aarin gbungbun.

Asiko taa wa yii ki i ṣe eyi to dara fun Sẹnetọ Iyabọ Ọbasanjọ, oludije fun ipo aṣofin agba niluu Abuja, labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, nipinlẹ Ogun.

Idi abajọ ni ti idajọ tile ẹjọ giga ju iyẹn Supreme Court gbe kalẹ lori atunṣe ofin idibo tọdun 2026, eyi to nii ṣe pẹlu iforukọsilẹ ọmọ ẹgbẹ ati yiyan oludije.

Idajọ ọhun to waye lọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii lawọn onidajọ ti wọn jẹ ọmọ igbimọ meje ninu eyi ti Adajọ Adam Jauro jẹ olori fun ni wọn ti gba ẹjọ kotẹmilọrun ajọ eleto idibo, ti wọn si fagile ẹjọ kotẹmilọrun, ti wọn si gba ẹka 77, 5,6,7, ẹ wọle ninu ofin idibo ọdun 2026 wọle.

Wọn ni nnkan ti ofin naa sọ ni pe ẹni ti orukọ ẹ ba farahan gẹgẹ bi ọmọ ẹgbẹ ti wọn fi orukọ ẹ ranṣẹ si ajọ eleto idibo ni ọjọ kọkanlelogun ki pamari to waye lo le kopa lati dije.Ẹgbẹ oṣelu ko gbọdọ forukọ ẹnikẹni silẹ lẹyin akoko yii. Ẹgbẹ oṣelu to ba kuna lati forukọ silẹ lawọn akoko ọhun yoo padanu aye tabi ipo naa.

Ohun to wa jẹ ki ọrọ naa kan Iyabọ Ọbasanjọ to fi ko sinu idaamu bayii ni pe ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ni, nibi to ti kopa nibi igbesẹ ẹgbẹ ọhun lati yan gomina. O kọwe lati fi ẹgbẹ silẹ ni Ọgbọnjọ, oṣu karun-un ọdun 2026, o si kede sita lọjọ kẹjọ, oṣu kẹfa, nigba ti PDP gba a sinu ẹgbẹ lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kẹfa nigba ti yoo fi di ọjọ kẹtadinlogun, wọn ti fun un ni tikẹẹti oludije fun ipo Ogun Central..

Bo tilẹ jẹ pe ile ẹjọ giga julọ ko darukọ pato pe Iyabọ Ọbasanjọ gẹgẹ bi ẹni ti ofin naa mu amọ awọn tọrọ ye ti wọn si mọ nipa agbekalẹ idajọ to waye ọhun mọ pe inu ewu lobinrin naa wa pẹlu ibo ọdun to n bọ naa.

No comments:

Post a Comment

Pages