Ninu atẹjade kan ti Ọgbẹni Ọlanrewaju Adeṣina, akọwe olupolongo ẹgbẹ naa fi sita lo ti ṣalaye pe Jimi Lawal loun fi fi ẹmi imoore han si awọn adari ọhun fawọn ogun ti wọn ti la kọja sẹyin.
Ayẹyẹ ọjọọbi naa to waye ni Itoko, niluu Abẹokuta, lo tun jẹ bi ayẹyẹ onibeji nitori wọn tun fi sami bi ile ẹjọ kotẹmilọrun ṣe da ẹjọ ti wọn pe lati fi tako idajọ to gbe oludije naa wọle nu.
Lawal sọ pe oun mọ ọn mọ ṣe ayẹyẹ ọjọọbi pẹlu awọn eeyan naa ki gbogbo agbaye fi le mọ pe ẹbi kan naa ni wọn ninu ẹgbẹ oṣelu ADC.
O lo akoko naa lati fi tubọ pe fun iṣọkan ati ifẹ ninu ADC ipinkẹ Ogun ki ọwọ wọn fi le tẹ nnkan ti wọn n wa.
Lawal wa rọ awọn eeyan ipinlẹ Ogun lati dide ṣatilẹyin fun erongba oun lati di Gomina ninu ibo ọdun 2027.
Ninu ọrọ alaga ẹgbẹ naa, Ọtunba Fẹmi Ṣoluade, oun naa dupẹ lọwọ Ọlọrun fawọn ohun ti wọn ti la a kọja ṣẹyin, bẹẹ lo tun gboriyin fawọn ọmọ ẹgbẹ fun iforiti ati afojusun wọn pẹlu.
Bẹẹ lo rọ wọn lati tẹsiwaju nipa ilakaka wọn ki ẹgbẹ naa le ṣe aṣeyọri nibi ibo to n bọ.
Ọpọ ọrọ iwuri lawọn adari ẹgbẹ naa tun sọ lọjọ naa
No comments:
Post a Comment