Nibi ipade kan to ṣe pẹlu awọn alaga ẹgbẹ oṣelu ipinlẹ Ogun ti wọn jẹ IPAC, eyi to waye niluu Abẹokuta lo tun ti ṣeleri pe oun ko ni rẹwẹsi lati ja fitafita lori wahala to n waye ọhun.
Bẹẹ lo tun ṣalaye pe oun yoo rii pe okodoro ootọ yọju ati pe oun ko nii gba iyanjẹ laaye, nitori ọjọ iwaju.
Hunye tun fikun ọrọ ẹ pe iyalẹnu lo jẹ pe awọn ọmọ bibi ipinlẹ Ogun yoo maa woran lati ta ki gbogbo nnkan to jẹ alumọni ilẹ ati ọjọ iwaju fun ẹni ti kii ṣe ọmọ ipinlẹ ọhun.
O ṣalaye siwaju pe ero ọkan ko tako ẹnikẹni lati dije gẹgẹ bi ẹtọ ẹ lorileede yii ṣugbọn nnkan toun ja fun ni pe ibi ti onitọhun ti jade.
Hunye ni bawo lawọn ṣe le nigbẹkẹle ninu ẹni ti ki i sọmọ bibi ipinlẹ kan ti wọn ba gbe gbogbo alumọni wọn lee lọwọ.
O ni, Emi ko tako pe eeyan jade dupo lati ibikibi to ba wuu lati dije amọ irọ ni mi o fẹẹ, ki o ma filuu oniluu parọ pe ibẹ ni wọn ti bi ẹ, iyẹn gan an ni mo n ja fun."
Ẹni to ti figba kan jẹ kọmiṣanna tun ṣalaye pe awọn eeyan le gba ẹ gbọ, amọ to ile ti wọn ba fi irọ mọ, ko le duro.
O wa ṣeleri pe labẹ bo ti wu ko ri oun ko ni juwọ silẹ lori ijangbara toun ja yii.
Ninu ọrọ Sunday Ọlapọsi Ọginni, to jẹ akapo ẹgbẹ IPAC lapapọ ṣalaye pe ẹgbẹ wọn yoo ṣiṣẹ lori awọn igbesẹ ti Hunye gbe wa siwaju wọn lai fikan bọkan ninu.
O wa gba Hunye lamọran lati tẹsiwaju ninu ifikunkukun pẹlu ẹgbẹ oṣelu APC ati pe gbogbo ibi to ba ti fẹ iranlọwọ lọwọ wọn awọn yoo dide.
Nigba toun naa sọrọ, Abayọmi Sanyaolu to jẹ alaga IPAC nipinlẹ Ogun, o ni gbogbo alaye ti oludije Gomina APC ṣe lori bi wọn ṣe fẹẹ fi ẹtọ ẹ du lawọn ti gbọ.
O ni inu oun dun pe gbogbo ibeere tawọn beeere lọwọ ẹ lo da wọn loun, tinu awọn si dun lee lori.
O gboriyin fun fawọn iwa ọmọluabi to hu lori bo ṣe n gba alaafia laaye latigba to ti bẹrẹ ijangbara yii.
Sanyaolu ni loootọ awọn kii ṣe ile ẹjọ, ṣugbọn ẹgbẹ wọn yoo gbe igbesẹ lati fikunlukun pẹlu a APC titi de ileeṣẹ aarẹ lati rii pe idajọ ododo waye.
No comments:
Post a Comment