Hunye bẹbẹ atilẹyin ipadabọ Tinubu fun saa keji - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday, 11 September 2026

Hunye bẹbẹ atilẹyin ipadabọ Tinubu fun saa keji

Bi abẹrẹ ba bọ silẹ boya ni wọn le ri mu iyẹn juwe bi ero ṣe pọ to nibi ipolongo ita gbangba kan ti apapọ ẹgbẹ oṣelu ti wọn forukọ silẹ iyẹn Coalition of Registered Political Parties CRPP ṣe fun ipadabọ Aṣiwaju Bọla Tinubu.

Ayẹyẹ ọhun lo waye ni Ake, niluu Abẹokuta lọjọbọ, Tọsidee, nibi tawọn alatilẹyin awọn ẹgbẹ oṣelu ti pejupesẹ, ti agba olorin fuji nni Alaaji Ṣẹfiu Alao ṣere fun wọn.

Pabanbari ohun to waye lọjọ naa ni bi wdwwwwdswswswsss ṣe pọ rẹpẹtẹ lẹyin Abayọmi Hunye, ẹni ti awuyewuye ṣi n waye lọri ipo gomina to dije fun labẹ ẹgbẹ oṣelu APC ipinlẹ Ogun.

Eyi to tako aheso ọrọ tawọn alatako ẹ nidii oṣelu sọ pe ẹni to fẹẹ ṣe gomina ti ko lero lẹyin. Ṣe lawọn ọmọláẹyin ẹ pọ ti wọn si wa ṣatilẹyin fun un lọjọ naa.

Ninu ọrọ Hunye lọjọ naa lo ti gboriyin fawọn aṣeyọri iṣẹ akanṣe tijọba Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu ti ṣe ni saa akọkọ to ti fẹẹ pari nipa ọrọ aje ati imuayedẹrun.

O wa rọ awọn ọmọ bibi ipinlẹ Ogun lati ṣatilẹyin to gboogi fun ipadabọ Tinubu lẹẹkeji gẹgẹ bi aarẹ orileede yii.

O sọ siwaju pe  Tinubu ninu iṣakoso ẹ ti ran awọn ọmọ orileede yii lọwọ nipa mimu wọn kuro nibi ti wọn wa tẹlẹ.

Hunye wa tun kan sara si Tinubu lori ilakaka ẹ lori ẹkọ, eyi to fi ṣafiiwe Oloogbe Ọbafẹmi Awolọwọ.

O ni idaniloju wa pe bi Tinubu ba wọle ẹlẹẹkeji labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, idagbasoke yoo tubọ de ba ipinlẹ Ogun pẹlu.

O tun lo akoko naa lati kesi awọn araalu lati ma ṣe tẹti si awọn ọrọ ti ko mu itumọ da ni, ti wọn sọ pe awọn pada sẹyin.

Hunye ni kaka ki wọn maa fa sẹyin awọn yoo maa tẹsiwaju ni.

Ninu ọrọ Kọmureedi Sunday Ọlapọsi Ọginni, to jẹ alaga CRPP nipinlẹ Ogun, lo ti sọ pe ẹgbẹ naa wa nibẹ lati ṣatilẹyin fun Tinubu nitori awọn atunṣe to ti mu ba imayedẹrun ati ọrọ aje.

Bẹẹ lo rọ gbogbo ọmọ Naijiria lati lo ibo wọn fi gbe Tinubu wọle lẹẹkeji.

No comments:

Post a Comment

Pages