Bakan naa ni wọn tun sọ pe ko si ootọ ọrọ pe awọn ti gbe ẹjọ ti wọn pe oludije naa kuro nile ẹjọ, ti wọn lawọn kan tan an kalẹ kaakiri.
Ọrọ yii waye nibi ipade oniroyin tawọn ẹgbẹ oṣelu mejeeji naa pe nibi tawọn alaga wọn ti pariwo sita pe ahesọ lasan ni.
Ninu ọrọ Ọnarebu Adeyẹmi Solomon Oluwaṣeyifunmi alagba ẹgbẹ oṣelu YPP ati Abiọdun Akerele John ti ẹgbẹ BOOT,ni wọn ti tako iroyin ọhun ti wọn si sọ pe ko sẹni to bu awọn gbọ, ko to di pe wọn gbe e jade.
Wọn sọ pe bigba ti wọn fẹẹ ṣi awọn araalu lọkan niroyin ọhun ati pe titi di akoko yii ko ṣẹni to yọwọ yọsẹ ninu awọn to pe ẹjọ ọhun.
Bẹẹ ni wọn tun sọ pe ko ṣẹni tawọn ba a sọ tabi paṣẹ fun lori igbẹjọ naa pe ki wọn jawọ.
Iwadii tiẹ jẹ ka mọ pe Oluwaṣeyifunmi to jẹ alaga ẹgbẹ oṣelu YPP ko tiẹ mọ nnkankan bẹẹ ni wọn ko buu gbọ,ko to di wọn kede pe wọn lawọn ko ṣe ẹjọ mọ.
Wọn wa sọ pe igbẹjọ ile ẹjọ kọja nnkan ti wọn le fọwọ oṣelu mu ati pe ilana akọsilẹ ofin gbọdọ di amulo.
Alaga ẹgbẹ oṣelu BOOT ati YPP wa oloṣelu tọrọ kan naa lati jẹ ki ileeṣẹ eto idajọ ṣiṣẹ wọn gẹgẹ bi iṣẹ wọn lori awọn nnkan ti wọn pẹ ẹjọ naa fun.
Wọn fikun ọrọ wọn pe kii ṣe pe awọn lẹmi ikorira si Yayi bi ko ṣe pe awọn fẹẹ ki ofin ṣiṣẹ ọwọ ẹ fun eto ijọba tiwa-n-tiwa orileede yii.
Awọn alaga naa kesi Aarẹ Tinubu to tun adari ẹgbẹ APC lati pe Yayi lorukọ to n jẹ lati sọra ṣiṣi awọn eeyan lọkan, ko si jẹ ki idajọ ododo waye.
Wọn wa fẹsun kan Abayọmi Arabanbi ati Awolọla Awofaya Awoniyi lori ipa ti wọn ni wọn n ko lori igbẹjọ naa.
Bakan naa ni wọn lo akoko yii lati ke si awọn ẹṣọ alaabo nitori ẹmi wọn, wọn lawọn ripasẹ awọn alamin kan ti wọn tọpasẹ wọn lori ọrọ yii.
Ni ipari, wọn rọ gbogbo awọn araalu,ẹlẹgbẹjẹgbẹ to fi mọ awọn oniroyin lati ma ṣe tẹti si pe awọn ti jawọ ninu ẹjọ ọhun, wọn ni digbi lawọn ba ẹjọ naa lọ.
No comments:
Post a Comment