Lọjọ Aje, Mọnde, ni ẹgbẹ kan to wa fun ijiroro feto idibo ọdun 2027, iyẹn 'Conversation Team', ṣabẹwo sọdọ apapọ ẹgbẹ oṣelu nipinlẹ Ogun, iyẹn IPAC, nibi ti wọn ti jọ fimọsọkan lori ibo ọdun to n bọ.
Ọgbẹni Yinka Fọlarin lo ṣaaju awọn ọmọ ẹgbẹ ọhun wa ṣabẹwo sawọn IPAC, eyi to waye ni Ake, niluu Abẹokuta.
Ninu ọrọ ẹ, Fọlarin ṣalaye idi pataki ti wọn fi da ẹgbẹ naa silẹ.O sọ pe eto n lọ lọwọ lori bi wọn yoo ṣe pe gbogbo oludije fun ipo gomina ati aṣofin agba to fi mọ aṣoju ṣofin papọ nibi ti wọn yoo ti sọ nnkan ti wọn ni lọkan fawọn araalu ti wọn ba wọle.
O ṣalaye pe ẹgbẹ ijiroro ti wọn da silẹ lo jẹ ti ajọṣepọ ẹlẹgbẹjẹgbẹ awọn ajafẹtọọ to fi mọ awọn oniroyin,lati rii pe idibo ọdun to n bọ lọ nirọwọ rọṣẹ.
Fọlarin tun fikun ọrọ ẹ awọn fẹẹ ki ẹgbẹ apapọ oṣelu iyẹn IPAC kopa ninu eto ti wọn la silẹ, nitori awọn ti rawọn ipa ti wọn ti ko fun ilọsiwaju ati igbega nidii oṣelu to n lọ lọwọ.
O ṣọ pe ijiroro pẹlu awọn oludije gomina ọhun yoo waye niluu Abẹokuta nigba tawọn aṣofin apapọ yooku yoo waye kaakiri ẹkun mẹtẹẹta to wa nipinlẹ Ogun.
Fọlarin wa bẹbẹ fun ifọwọsowọpọ ẹgbẹ oṣelu IPAC nitori o lawọn mọ pe onikaluku ẹgbẹ oṣelu lo ni oludije ti wọn fẹẹ dije fun ibo to n bọ naa.
Ninu ọrọ alaga IPAC,Kọmureedi Abayọmi Sanyaolu, o fi idunnu ẹ han lori eto nla tawọn ẹgbẹ ijiroro lori ibo to n bọ naa fẹẹ ṣe, o wa gboriyin fawọn to ṣagbekalẹ ẹ
O wa fi aidunnu ẹ han lori ọna ibi ti oṣelu tun fẹẹ maa gbọna yọ, nitori bi wọn ṣe fẹẹ ma lo awọn janduku, ni eyi ti ko yẹ ko ri bẹ.
O sọ pe awọn ṣetan lati ṣiṣẹ pọ pẹlu ẹgbẹ naa fun ilọsiwaju ati idagbasoke fun eto oṣelu ọdun to n bọ.
No comments:
Post a Comment